Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  April 2016

April 11 sí 17

JÓÒBÙ 21-27

April 11 sí 17
 • Orin 83 àti Àdúrà

 • Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (3 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

 • Jóòbù Kò Fàyè Gba Èrò Òdì”: (10 min.)

  • Job 22:2-7—Élífásì dá lórí èrò èké àti èrò tara rẹ̀ (w06 3/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 7; w05 9/15 ojú ìwé 26 àti 27; w95 2/15 ojú ìwé 27 ìpínrọ̀ 6)

  • Job 25:4, 5—Ọ̀rọ̀ tí kì í ṣe òótọ́ ni Bílídádì sọ (w05 9/15 ojú ìwé 26 àti 27)

  • Job 27:5, 6—Jóòbù kò jẹ́ kí àwọn èèyàn mú kó máa rò pé òun ò pa ìwà títọ́ òun mọ́ (w09 8/15 ojú ìwé 4 ìpínrọ̀ 8; w06 3/15 ojú ìwé 15 ìpínrọ̀ 9)

 • Máa Walẹ̀ Jìn Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run: (8 min.)

  • Job 24:2—Kí nìdí tí sísún ààlà sẹ́yìn fí jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ tó burú jáì (it-1-E ojú ìwé 360)

  • Job 26:7—Kí nìdí tí ohun tí Jóòbù sọ nípa ayé fi ṣe pàtàkì? (w15 6/1 ojú ìwé 5 ìpínrọ̀ 4; w11 7/1 ojú ìwé 26 ìpínrọ̀ 2 sí 5)

  • Ẹ̀kọ́ wo ni Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí kọ́ mi nípa Jèhófà?

  • Àwọn kókó wo látinú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí ni mo lè lò lóde ẹ̀rí?

 • Bíbélì Kíkà: Job 27:1-23 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)

MÁA LO ARA RẸ LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

 • Orin 129

 • Bó O Ṣe Lè Borí Ẹni Tó Ń Halẹ̀ Mọ́ Ẹ Láì Bá A Jà: (15 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo fídíò eré ojú pátákó tá a pe àkọlé rẹ̀ ní Bó O Ṣe Lè Borí Ẹni Tó Ń Halẹ̀ Mọ́ Ẹ Láì Bá A Jà. (Lọ sí jw.org/yo, kó o sì wo abẹ́ Ẹ̀KỌ́ BÍBÉLÌ > ÀWỌN Ọ̀DỌ́.) Lẹ́yìn náà, ẹ jíròrò àwọn ìbéèrè yìí: Kí nìdí tí wọ́n fi lè máa halẹ̀ mọ́ ẹnì kan? Ìpalára wo ni híhalẹ̀ mọ́ni máa ń fà? Báwo lo ṣe lè borí ẹni tó ń halẹ̀ mọ́ ẹ tàbí kó o yẹra fún un? Ta lo lè sọ fún tí wọ́n bá ń halẹ̀ mọ́ ẹ? Tọ́ka sí orí 14 ìwé Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè, Apá 2.

 • Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ: ia orí 13 ìpínrọ̀ 1 sí 12 (30 min..)

 • Àtúnyẹ̀wò àti Ohun Tá A Máa Kọ́ Lọ́sẹ̀ Tó Ń Bọ̀ (3 min.)

 • Orin 23 àti Àdúrà