Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Àwa Kristẹni—Ìwé Ìpàdé  |  April 2016

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò

JÍ!

Fi ìwé lọni: Mo mú ìwé ìròyìn Jí! tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde yìí wá fún yín

Béèrè ìbéèrè: Ẹ wo ìbéèrè tó wà lójú ìwé 2 yìí. Ẹ jọ̀wọ́, kí lèrò yín nípa rẹ̀?

Ka Bíbélì: Lk 7:35

Àpilẹ̀kọ yìí sọ̀rọ̀ nípa bí ohun tá a kà yìí ṣe fi hàn pé ìwé ọgbọ́n ni Bíbélì.

JÍ!

Béèrè ìbéèrè: Ǹjẹ́ ẹ gbà pé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó yẹ ká máa fi sílò ni ọ̀rọ̀ yìí?

Ka Bíbélì: Mt 6:34

Fi ìwé lọni: [Ṣí ìwé ìròyìn náà sí àpilẹ̀kọ tó ní àkorí náà “Ìwòye Bíbélì—Àníyàn.”] Àpilẹ̀kọ yìí jẹ́ ká mọ bí Bíbélì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àníyàn.

Bíbélì Fi Kọ́ni

Béèrè ìbéèrè: Ọ̀pọ̀ àwọn tó gbà pé Ọlọ́run wà ló máa ń fẹ́ sún mọ́ ọn. Ǹjẹ́ ẹ mọ̀ pé Bíbélì sọ pé ká sún mọ́ Ọlọ́run?

Ka Bíbélì: Jak 4:8a

Fi ìwé lọni: A ṣe ìwé yìí ká lè fi kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Ọlọ́run nínú Bíbélì. [Fi orí 1 han onílé nínú ìwé Bíbélì Fi Kọ́ni.]

KỌ Ọ̀NÀ ÌGBỌ́RỌ̀KALẸ̀ RẸ

Wo àwọn ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tá a fi ṣe àpẹẹrẹ yìí, kó o sì kọ ọ̀nà ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ tìrẹ.