Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Títù 3:1-15

3  Máa bá a lọ ní rírán wọn létí láti wà ní ìtẹríba+ àti láti jẹ́ onígbọràn sí àwọn ìjọba àti àwọn aláṣẹ gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso,+ láti gbára dì fún iṣẹ́ rere gbogbo,+  láti má sọ̀rọ̀ ẹnì kankan lọ́nà ìbàjẹ́, láti má ṣe jẹ́ aríjàgbá,+ láti jẹ́ afòyebánilò,+ kí wọ́n máa fi gbogbo ìwà tútù hàn sí ènìyàn gbogbo.+  Nítorí àwa pàápàá nígbà kan rí jẹ́ òpònú, aláìgbọràn, ẹni tí a ṣì lọ́nà, ẹrú fún onírúurú ìfẹ́-ọkàn àti adùn, tí a ń bá a lọ nínú ìwà búburú àti ìlara, a jẹ́ ẹni ìkórìíra tẹ̀gàntẹ̀gàn, a kórìíra ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.+  Àmọ́ ṣá o, nígbà tí inú rere+ àti ìfẹ́ fún ènìyàn níhà ọ̀dọ̀ Olùgbàlà wa,+ Ọlọ́run, di èyí tí a fi hàn kedere,+  kì í ṣe nítorí iṣẹ́+ òdodo kankan tí àwa ti ṣe,+ ṣùgbọ́n ní ìbámu pẹ̀lú àánú rẹ̀,+ ó gbà wá là nípasẹ̀ ìwẹ̀+ tí ó mú wa wá sí ìyè+ àti nípa sísọ wa di tuntun nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́.+  Ẹ̀mí yìí ni ó tú jáde lọ́pọ̀ jaburata sórí wa nípasẹ̀ Jésù Kristi Olùgbàlà wa,+  pé, lẹ́yìn pípolongo wa ní olódodo+ nítorí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí ẹni yẹn,+ kí a lè di ajogún+ ní ìbámu pẹ̀lú ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun.+  Àsọjáde náà ṣeé gbíyè lé,+ mo sì fẹ́ kí o máa ṣe ìtẹnumọ́ tí ó fìdí múlẹ̀ nípa nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo, kí àwọn tí ó ti gba Ọlọ́run gbọ́ bàa lè máa gbé èrò inú wọn ka orí dídi àwọn iṣẹ́ àtàtà mú.+ Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì ṣàǹfààní fún ènìyàn.  Ṣùgbọ́n máa yẹ àwọn ìbéèrè òmùgọ̀+ sílẹ̀ àti àwọn ìtàn ìlà ìdílé+ àti gbọ́nmi-si omi-ò-to+ àti àwọn ìjà lórí Òfin,+ nítorí tí wọ́n jẹ́ aláìlérè àti ìmúlẹ̀mófo. 10  Ní ti ẹni tí ń ṣe agbátẹrù ẹ̀ya ìsìn,+ kọ̀ ọ́ tì+ lẹ́yìn ìṣílétí kìíní àti èkejì;+ 11  ní mímọ̀ pé irúfẹ́ ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ti yí padà kúrò lójú ọ̀nà, ó sì ń dẹ́ṣẹ̀, ó ti dá ara rẹ̀ lẹ́bi.+ 12  Nígbà tí mo bá rán Átémásì tàbí Tíkíkù sí ọ,+ sa gbogbo ipá rẹ láti wá sọ́dọ̀ mi ní Nikopólísì, nítorí ibẹ̀ ni mo ti pinnu láti lo ìgbà òtútù.+ 13  Fara balẹ̀ pèsè fún Sénásì, ẹni tí ó jẹ́ ògbóǹkangí nínú Òfin, àti Àpólò fún ìrìnnà àjò wọn, kí wọ́n má bàa ṣaláìní ohunkóhun.+ 14  Ṣùgbọ́n kí àwọn ènìyàn wa kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú láti di àwọn iṣẹ́ àtàtà mú, kí wọ́n lè máa pèsè fún àwọn àìní wọn kánjúkánjú,+ kí wọ́n má bàa jẹ́ aláìléso.+ 15  Gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú mi kí ọ.+ Bá mi kí àwọn tí ó ní ìfẹ́ni fún wa nínú ìgbàgbọ́. Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí wà pẹ̀lú gbogbo yín.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé