Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Títù 1:1-16

1  Pọ́ọ̀lù, ẹrú+ Ọlọ́run àti àpọ́sítélì+ Jésù Kristi ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ àwọn ẹni àyànfẹ́+ Ọlọ́run àti ìmọ̀ pípéye+ nípa òtítọ́+ tí ó wà ní ìbámu pẹ̀lú fífọkànsin Ọlọ́run+  nípa ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun,+ èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí kò lè purọ́,+ ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́,+  nígbà tí ó jẹ́ pé ní àwọn àkókò yíyẹ tirẹ̀, ó fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn kedere nínú ìwàásù tí a fi sí ìkáwọ́ mi,+ lábẹ́ àṣẹ Olùgbàlà wa,+ Ọlọ́run;  sí Títù, ojúlówó ọmọ+ ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tí a ṣàjọpín ní àpapọ̀: Kí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí àti àlàáfíà wà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba+ àti Kristi Jésù Olùgbàlà wa.+  Fún ìdí yìí ni mo fi fi ọ́ sílẹ̀ ní Kírétè,+ kí o lè ṣe àtúnṣe àwọn ohun tí ó ní àbùkù, kí o sì lè yan àwọn àgbà ọkùnrin sípò+ láti ìlú ńlá dé ìlú ńlá, gẹ́gẹ́ bí mo ti fún ọ ní àwọn àṣẹ ìtọ́ni;+  bí ọkùnrin èyíkéyìí bá wà láìní ẹ̀sùn lọ́rùn,+ ọkọ aya kan,+ tí ó ní àwọn ọmọ tí wọ́n gbà gbọ́, tí wọn kò sí lábẹ́ ẹ̀sùn ìwà wọ̀bìà tàbí ya ewèlè.+  Nítorí alábòójútó gbọ́dọ̀ wà láìní ẹ̀sùn lọ́rùn+ gẹ́gẹ́ bí ìríjú Ọlọ́run,+ kì í ṣe aṣetinú-ẹni,+ kì í ṣe ẹni tí ó ní ìtẹ̀sí fún ìrunú,+ kì í ṣe aláriwo ọ̀mùtípara,+ kì í ṣe aluni,+ kì í ṣe oníwọra fún èrè àbòsí,+  bí kò ṣe ẹni tí ó ní ẹ̀mí aájò àlejò,+ olùfẹ́ ohun rere, ẹni tí ó yè kooro ní èrò inú,+ olódodo, adúróṣinṣin,+ ẹni tí ń kó ara rẹ̀ níjàánu,+  tí ń di ọ̀rọ̀ ṣíṣeégbíyèlé mú ṣinṣin ní ti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀,+ kí ó bàa lè gbani níyànjú pẹ̀lú ẹ̀kọ́ afúnni-nílera+ àti láti fi ìbáwí tọ́ àwọn tí ń ṣàtakò sọ́nà.+ 10  Nítorí ọ̀pọ̀ ewèlè ènìyàn ni ó wà, àwọn asọ̀rọ̀ tí kò lérè,+ àti àwọn tí ń tan èrò inú jẹ, ní pàtàkì àwọn ènìyàn tí wọ́n rọ̀ mọ́ ìdádọ̀dọ́.+ 11  Ó pọndandan láti pa ẹnu àwọn wọ̀nyí mọ́, níwọ̀n bí àwọn ènìyàn wọ̀nyí pàápàá ti ń bá a nìṣó ní dídojú gbogbo àwọn agbo ilé pátá dé+ nípa kíkọ́ni ní àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n fi kọ́ni nítorí èrè àbòsí.+ 12  Ẹnì kan nínú wọn, wòlíì tiwọn, wí pé: “Àwọn ará Kírétè jẹ́ òpùrọ́ nígbà gbogbo, ẹranko ẹhànnà tí ń ṣeni léṣe,+ àwọn alájẹkì tí kò níṣẹ́ lọ́wọ́.” 13  Òótọ́ ni ẹ̀rí yìí. Fún ìdí yìí gan-an, máa bá a nìṣó ní fífi ìbáwí tọ́ wọn sọ́nà pẹ̀lú ìmúnájanjan,+ kí wọ́n lè jẹ́ onílera+ nínú ìgbàgbọ́, 14  ní ṣíṣàìfiyèsí àwọn ìtàn àlọ́ Júù+ àti àṣẹ àwọn ènìyàn+ tí wọ́n yí ara wọn padà kúrò nínú òtítọ́.+ 15  Ohun gbogbo ni ó mọ́ fún àwọn tí ó mọ́.+ Ṣùgbọ́n fún àwọn tí ó jẹ́ ẹlẹ́gbin+ àti aláìnígbàgbọ́,+ kò sí ohun tí ó mọ́, ṣùgbọ́n èrò inú wọn àti ẹ̀rí-ọkàn+ wọn jẹ́ ẹlẹ́gbin. 16  Wọ́n polongo ní gbangba pé àwọn mọ Ọlọ́run,+ ṣùgbọ́n wọ́n sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nípa àwọn iṣẹ́ wọn,+ nítorí tí wọ́n jẹ́ ẹni ìṣe-họ́ọ̀-sí àti aláìgbọràn, a kò sì tẹ́wọ́ gbà+ wọ́n fún iṣẹ́ rere èyíkéyìí.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé