Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sekaráyà 9:1-17

9  Ọ̀rọ̀ ìkéde:+ “Ọ̀rọ̀ Jèhófà jẹ́ lòdì sí ilẹ̀ Hádírákì, Damásíkù+ sì ni ó balẹ̀ sí; nítorí ojú Jèhófà wà lára ará ayé+ àti lára gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì.  Hámátì+ pẹ̀lú yóò sì fara ti ojú ààlà rẹ̀; Tírè+ àti Sídónì,+ nítorí òun jẹ́ ọlọ́gbọ́n gidigidi.+  Tírè sì tẹ̀ síwájú láti mọ ohun àfiṣe-odi fún ara rẹ̀, àti láti to fàdákà jọ pelemọ bí ekuru àti wúrà bí ẹrẹ̀ ojú pópó.+  Wò ó! Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò lé e kúrò, inú òkun ni òun yóò sì ṣá ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ balẹ̀ sí;+ inú iná ni a ó sì ti jẹ òun fúnra rẹ̀ run.+  Áṣíkẹ́lónì yóò rí i, yóò sì fòyà; àti ní ti Gásà, òun pẹ̀lú yóò jẹ̀rora mímúná gan-an; Ékírónì+ pẹ̀lú, nítorí pé ìretí tí ó ń wọ̀nà fún+ yóò ní ìrírí ìtìjú. Dájúdájú, ọba yóò sì ṣègbé kúrò ní Gásà, a kì yóò sì gbé ní Áṣíkẹ́lónì pàápàá.+  Ọmọ àlè+ yóò sì jókòó ní ti tòótọ́ ní Áṣídódì,+ dájúdájú, èmi yóò sì ké ìyangàn Filísínì kúrò.+  Ṣe ni èmi yóò sì mú àwọn ohun alábààwọ̀n-ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ kúrò ní ẹnu rẹ̀ àti àwọn ohun ìríra rẹ̀ kúrò láàárín eyín rẹ̀,+ dájúdájú, òun alára ni yóò sì ṣẹ́ kù fún Ọlọ́run wa; òun yóò sì dà bí séríkí+ ní Júdà,+ Ékírónì yóò sì dà bí ará Jébúsì.+  Ṣe ni èmi yóò sì dó bí ọ̀wọ́ ọmọ ogun ẹ̀yìn ibùdó fún ilé mi,+ tí kò fi ní sí ẹni tí ń gba ibẹ̀ kọjá, tí kò sì fi ní sí ẹni tí ń gba ibẹ̀ padà; akóniṣiṣẹ́+ kì yóò sì gba àáarín wọn kọjá mọ́, nítorí pé mo ti fi ojú mi rí i nísinsìnyí.+  “Kún fún ìdùnnú gidigidi, ìwọ ọmọbìnrin Síónì.+ Kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun,+ ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù. Wò ó! Ọba rẹ+ fúnra rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá.+ Ó jẹ́ olódodo, bẹ́ẹ̀ ni, ẹni ìgbàlà;+ onírẹ̀lẹ̀,+ ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ẹran tí ó ti dàgbà tán, ọmọ abo kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.+ 10  Dájúdájú, èmi yóò sì ké kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun kúrò ní Éfúráímù àti ẹṣin kúrò ní Jerúsálẹ́mù.+ Ọrun ìjà ogun+ ni a ó sì ké kúrò. Òun yóò sì sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí àwọn orílẹ̀-èdè ní ti tòótọ́;+ agbára ìṣàkóso rẹ̀ yóò sì jẹ́ láti òkun dé òkun àti láti Odò dé òpin ilẹ̀ ayé.+ 11  “Pẹ̀lúpẹ̀lù, ìwọ, obìnrin, nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú+ rẹ ni èmi yóò rán àwọn ẹlẹ́wọ̀n+ rẹ jáde kúrò nínú kòtò tí kò sí omi. 12  “Ẹ padà sí ibi odi agbára,+ ẹ̀yin ẹlẹ́wọ̀n tí ó ní ìrètí.+ “Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo ń sọ fún ọ lónìí pé, ‘Èmi yóò san án padà fún ọ, ìwọ obìnrin, ní ìlọ́po méjì.+ 13  Nítorí èmi yóò fa Júdà gẹ́gẹ́ bí ọrun mi. Ọrun ni èmi yóò fi Éfúráímù kún, èmi yóò sì jí àwọn ọmọ rẹ,+ ìwọ Síónì, ní ìdojú-ìjà-kọ àwọn ọmọ rẹ, ìwọ ilẹ̀ Gíríìsì,+ èmi yóò sì ṣe ọ́ bí idà ọkùnrin alágbára ńlá.’+ 14  A ó sì rí Jèhófà fúnra rẹ̀ lórí wọn,+ dájúdájú, ọfà rẹ̀ yóò sì jáde lọ bí mànàmáná.+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fúnra rẹ̀ yóò sì fun ìwo,+ dájúdájú, òun yóò sì lọ pẹ̀lú ìjì ẹlẹ́fùúùfù ti gúúsù.+ 15  Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun fúnra rẹ̀ yóò gbèjà wọn, ní ti tòótọ́, wọn yóò sì jẹ run,+ wọn yóò sì tẹ òkúta kànnàkànnà lórí ba. Dájúdájú, wọn yóò sì mu+—wọn yóò di aláriwo líle—bí ẹni pé wáìnì wà; ní ti tòótọ́, wọn yóò sì kún bí àwokòtò, bí àwọn igun pẹpẹ.+ 16  “Dájúdájú, Jèhófà Ọlọ́run wọn yóò sì gbà wọ́n là+ ní ọjọ́ yẹn bí agbo àwọn ènìyàn rẹ̀;+ nítorí wọn yóò dà bí òkúta adé dáyádémà tí ń dán yinrinyinrin lórí ilẹ̀ rẹ̀.+ 17  Nítorí wo bí oore rẹ̀ ti pọ̀ tó,+ sì wo bí ìrẹwà rẹ̀ ti pọ̀ tó!+ Ọkà ni yóò mú kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin gbèrú, wáìnì tuntun ni yóò sì mú kí àwọn wúńdíá gbèrú.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé