Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sekaráyà 8:1-23

8  Ọ̀rọ̀ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun sì ń bá a lọ láti wá, pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí,+ ‘Ṣe ni èmi yóò fi owú ńláǹlà jowú fún Síónì,+ ìhónú ńláǹlà+ sì ni èmi yóò fi jowú fún un.’”  “Èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘Èmi yóò padà sí Síónì,+ èmi yóò sì máa gbé ní àárín Jerúsálẹ́mù;+ dájúdájú, a ó sì pe Jerúsálẹ́mù ní ìlú ńlá òótọ́,+ a ó sì pe òkè ńlá Jèhófà+ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní òkè ńlá mímọ́.’”+  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Àwọn arúgbó ọkùnrin àti àwọn arúgbó obìnrin yóò ṣì jókòó ní àwọn ojúde ìlú Jerúsálẹ́mù,+ olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá+ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ nítorí ọ̀pọ̀ yanturu àwọn ọjọ́ rẹ̀.  Àní àwọn ojúde ìlú ńlá náà yóò sì kún fún àwọn ọmọdékùnrin àti àwọn ọmọdébìnrin tí ń ṣeré ní àwọn ojúde rẹ̀.’”+  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó jọ ohun tí ó ṣòro jù ní ojú àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ènìyàn yìí ní ọjọ́ wọnnì, ó ha yẹ kí ó jọ ohun tí ó ṣòro jù ní ojú mi pẹ̀lú?’+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.”  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Kíyè sí i, èmi yóò gba àwọn ènìyàn mi là láti ilẹ̀ yíyọ oòrùn àti láti ilẹ̀ wíwọ̀ oòrùn.+  Dájúdájú, èmi yóò sì mú wọn wá, wọn yóò sì máa gbé ní àárín Jerúsálẹ́mù;+ wọn yóò sì di ènìyàn mi,+ èmi alára yóò sì di Ọlọ́run wọn ní òótọ́ àti ní òdodo.’”+  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Ẹ jẹ́ kí ọwọ́ yín le,+ ẹ̀yin tí ẹ ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí láti ẹnu àwọn wòlíì,+ ní ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun lélẹ̀, láti kọ́ tẹ́ńpìlì.+ 10  Nítorí ṣáájú ọjọ́ wọnnì, kò sí owó ọ̀yà tí ó wà fún aráyé;+ àti ní ti owó ọ̀yà ti ẹran agbéléjẹ̀, kò sí ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀; àti fún ẹni tí ń jáde lọ àti fún ẹni tí ń wọlé bọ̀, kò sí àlàáfíà nítorí elénìní,+ bí mo ti ń ti gbogbo aráyé lu ara wọn.’+ 11  “‘Wàyí o, èmi kì yóò dà bí ti àwọn ọjọ́ àtijọ́ sí àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ènìyàn yìí,’+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. 12  ‘Nítorí irú-ọmọ àlàáfíà yóò wà;+ àní àjàrà yóò mú èso rẹ̀ wá,+ ilẹ̀ pàápàá yóò sì mú èso rẹ̀ jáde,+ ọ̀run pàápàá yóò sì fúnni ní ìrì rẹ̀;+ dájúdájú, èmi yóò sì mú kí àwọn tí ó ṣẹ́ kù+ lára àwọn ènìyàn yìí jogún gbogbo nǹkan wọ̀nyí.+ 13  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti di ìfiré láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ ìwọ ilé Júdà àti ilé Ísírẹ́lì,+ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò gbà yín là, ẹ óò sì di ìbùkún.+ Ẹ má fòyà.+ Kí ọwọ́ yín le.’+ 14  “Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘“Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti ní in lọ́kàn láti ṣe ohun tí ó jẹ́ ìyọnu àjálù sí yín nítorí àwọn baba ńlá yín tí ń mú ìkannú mi ru,”+ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, “èmi kò sì pèrò dà,+ 15  èmi yóò tún ní in lọ́kàn ní ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe dáadáa sí Jerúsálẹ́mù àti sí ilé Júdà.+ Ẹ má fòyà.”’+ 16  “‘Ìwọ̀nyí ni ohun tí ẹ ó ṣe:+ Ẹ bá ara yín sọ òtítọ́ lẹ́nì kìíní-kejì.+ Ẹ fi òtítọ́ àti ìdájọ́ àlàáfíà ṣe ìdájọ́ yín ní ẹnubodè yín.+ 17  Ẹ má sì pète-pèrò ìyọnu àjálù sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì ní ọkàn-àyà yín,+ ẹ má sì nífẹ̀ẹ́ ìbúra èké èyíkéyìí;+ nítorí ìwọ̀nyí ni gbogbo ohun tí mo kórìíra,’+ ni àsọjáde Jèhófà.” 18  Ọ̀rọ̀ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 19  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Ààwẹ̀ oṣù kẹrin,+ àti ààwẹ̀ oṣù karùn-ún,+ àti ààwẹ̀ oṣù keje,+ àti ààwẹ̀ oṣù kẹwàá+ yóò di ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ àti àkókò àjọyọ̀ rere fún ilé Júdà.+ Nítorí náà, nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.’+ 20  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Yóò ṣì ṣẹlẹ̀ pé àwọn ènìyàn àti àwọn olùgbé ọ̀pọ̀ ìlú ńlá yóò wá;+ 21  ṣe ni àwọn olùgbé ìlú ńlá kan yóò sì lọ sí òmíràn, pé: “Ẹ jẹ́ kí a fi taratara lọ+ láti tu Jèhófà lójú,+ kí a sì wá Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun. Èmi alára yóò lọ pẹ̀lú.”+ 22  Ọ̀pọ̀ ènìyàn àti àwọn orílẹ̀-èdè alágbára ńlá yóò sì wá ní ti tòótọ́ láti wá Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní Jerúsálẹ́mù+ àti láti tu Jèhófà lójú.’ 23  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì pé ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè+ yóò dì í mú,+ bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú,+ pé: “Àwa yóò bá yín lọ,+ nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé