Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sekaráyà 7:1-14

7  Síwájú sí i, ó ṣẹlẹ̀ pé ní ọdún kẹrin Dáríúsì+ Ọba, ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Sekaráyà wá, ní ọjọ́ kẹrin oṣù kẹsàn-án, èyíinì ni, Kísíléfì.+  Bẹ́tẹ́lì sì tẹ̀ síwájú láti rán Ṣárésà àti Regemu-mélékì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ láti tu Jèhófà lójú,+  ó wí fún àwọn àlùfáà+ tí ó jẹ́ ti ilé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àti fún àwọn wòlíì, àní ó wí pé: “Èmi yóò ha sunkún ní oṣù karùn-ún,+ kí ń wà nínú ìtakété, bí mo ti ṣe ní àwọn ọdún mélòó yìí wá?”+  Ọ̀rọ̀ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Sọ fún gbogbo ènìyàn ilẹ̀ náà àti fún àwọn àlùfáà pé, ‘Nígbà tí ẹ gbààwẹ̀,+ tí ìpohùnréré ẹkún sì wà ní oṣù karùn-ún àti ní oṣù keje,+ tí èyí sì jẹ́ fún àádọ́rin ọdún,+ ẹ ha gbààwẹ̀ sí mi ní tòótọ́, àní sí èmi?+  Nígbà tí ẹ bá jẹ àti nígbà tí ẹ bá mu, kì í há ṣe ẹ̀yin ni ẹni tí ń jẹ, kì í ha sì ṣe ẹ̀yin ni ẹni tí ń mu?  Kò ha yẹ kí ẹ ṣègbọràn sí àwọn ọ̀rọ̀+ tí Jèhófà ké jáde nípasẹ̀ àwọn wòlíì àtijọ́,+ nígbà tí a ṣì ń gbé Jerúsálẹ́mù, tí ó sì wà ní ìdẹ̀rùn, pẹ̀lú àwọn ìlú ńlá rẹ̀ tí ó yí i ká, àti nígbà tí a ṣì ń gbé Négébù+ àti Ṣẹ́fẹ́là?’”+  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ Sekaráyà wá, pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Ẹ fi ìdájọ́ òdodo tòótọ́ ṣe ìdájọ́ yín;+ kí ẹ sì máa bá a lọ ní ṣíṣe inú-rere-onífẹ̀ẹ́+ àti àánú+ sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; 10  ẹ má sì lu opó+ tàbí ọmọdékùnrin aláìníbaba,+ àtìpó+ tàbí ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́+ ní jìbìtì, ẹ má sì pète-pèrò nǹkan búburú sí ara yín lẹ́nì kìíní-kejì nínú ọkàn-àyà yín.’+ 11  Ṣùgbọ́n wọ́n ń kọ̀ láti fiyè sílẹ̀,+ wọ́n sì ń bá a lọ láti gún èjìká,+ wọ́n sì mú etí wọn gíràn-án kí ó má bàa gbọ́.+ 12  Wọ́n sì ṣe ọkàn-àyà+ wọn bí òkúta émérì láti má ṣègbọràn sí òfin+ àti sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun fi ránṣẹ́ nípasẹ̀ ẹ̀mí+ rẹ̀, nípasẹ̀ àwọn wòlíì àtijọ́;+ tí ìkannú ńláǹlà fi ṣẹlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.”+ 13  “‘Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti pè, tí wọn kò sì fetí sílẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò pè, èmi kì yóò sì fetí sílẹ̀,’+ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí. 14  ‘Mo sì tẹ̀ síwájú láti fi ìjì líle fi wọ́n sọ̀kò káàkiri gbogbo orílẹ̀-èdè+ tí wọn kò mọ̀;+ ilẹ̀ náà ni a sì ti fi sílẹ̀ ní ahoro lẹ́yìn wọn, láìsí ẹnì kankan tí ń là á kọjá, tí kò sì sí ẹnì kankan tí ń padà;+ wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti sọ ilẹ̀ fífani-lọ́kàn-mọ́ra náà+ di ohun ìyàlẹ́nu.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé