Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sekaráyà 6:1-15

6  Lẹ́yìn náà, mo tún gbé ojú mi sókè, mo sì rí i; sì wò ó! kẹ̀kẹ́ ẹṣin mẹ́rin wà tí ń jáde bọ̀ láti àárín òkè ńlá méjì, àwọn òkè ńlá náà sì jẹ́ òkè ńlá bàbà.  Àwọn ẹṣin pupa+ wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin àkọ́kọ́; àwọn ẹṣin dúdú+ sì wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin kejì.  Àwọn ẹṣin funfun+ wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin kẹta; àwọn ẹṣin aláwọ̀ tó-tò-tó, adíkálà,+ sì wà nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin kẹrin.  Mo sì tẹ̀ síwájú láti dáhùn, mo sì wí fún áńgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ pé: “Kí ni ìwọ̀nyí, olúwa mi?”+  Nítorí náà, áńgẹ́lì náà dáhùn, ó sì wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin+ ti ọ̀run tí ń jáde lọ+ lẹ́yìn tí wọ́n ti mú ìdúró wọn níwájú Olúwa+ gbogbo ilẹ̀ ayé.+  Ní ti èyí tí àwọn ẹṣin dúdú wà, wọ́n ń jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá;+ àti ní ti àwọn funfun, wọn yóò jáde lọ sí ẹ̀yìn òkun; àti ní ti àwọn aláwọ̀ tó-tò-tó, wọn yóò jáde lọ sí ilẹ̀ gúúsù.+  Àti ní ti àwọn adíkálà,+ wọn yóò jáde lọ, wọn yóò sì máa wá ibi tí wọn yóò lọ, kí wọ́n bàa lè rìn káàkiri ní ilẹ̀ ayé.” Lẹ́yìn náà, ó wí pé: “Lọ, rìn káàkiri ní ilẹ̀ ayé.”+ Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn káàkiri ní ilẹ̀ ayé.  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ké jáde sí mi, ó sì bá mi sọ̀rọ̀, pé: “Wò ó, àwọn tí ń jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá ni àwọn ẹni tí ó mú kí ẹ̀mí+ Jèhófà sinmi ní ilẹ̀ àríwá.”+  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé: 10  “Kí gbígba ohun kan láti ọwọ́ àwọn ìgbèkùn wáyé,+ àní láti ọwọ́ Hélídáì àti láti ọwọ́ Tóbíjà àti láti ọwọ́ Jedáyà; kí ìwọ fúnra rẹ sì wá ní ọjọ́ yẹn, kí o sì wá sí ilé Jòsáyà ọmọkùnrin Sefanáyà+ pẹ̀lú àwọn yìí tí ó wá láti Bábílónì. 11  Kí o sì mú fàdákà àti wúrà, kí o sì ṣe adé títóbi lọ́lá,+ kí o sì fi dé orí Jóṣúà+ ọmọkùnrin Jèhósádákì àlùfáà àgbà. 12  Kí o sì wí fún un pé, “‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Ọkùnrin náà+ rèé tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ìrújáde.+ Láti ipò rẹ̀ ni yóò sì ti rú jáde, dájúdájú, òun yóò sì kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà.+ 13  Òun fúnra rẹ̀ yóò sì kọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà, àti òun, ní tirẹ̀, yóò ru iyì;+ yóò sì jókòó, yóò sì ṣàkóso lórí ìtẹ́ rẹ̀, òun yóò sì di àlùfáà lórí ìtẹ́ rẹ̀,+ ìmọ̀ràn àlàáfíà+ gan-an yóò sì wà láàárín àwọn méjèèjì. 14  Adé títóbi lọ́lá náà yóò sì wá jẹ́ ti Hélémù àti Tóbíjà àti Jedáyà+ àti Hénì ọmọkùnrin Sefanáyà bí ìrántí+ nínú tẹ́ńpìlì Jèhófà. 15  Àwọn tí ó sì jìnnà réré yóò wá, ní ti tòótọ́, wọn yóò sì kọ́ lára tẹ́ńpìlì Jèhófà.”+ Ẹ ó sì ní láti mọ̀ pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun fúnra rẹ̀ ni ó rán mi sí yín.+ Yóò sì ṣẹlẹ̀—láìkùnà bí ẹ bá fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run yín.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé