Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sekaráyà 5:1-11

5  Lẹ́yìn náà, mo tún gbé ojú mi sókè, mo sì rí i; sì wò ó! àkájọ ìwé tí ń fò.+  Nítorí náà, ó wí fún mi pé: “Kí ni o rí?”+ Ẹ̀wẹ̀, mo wí pé: “Mo rí àkájọ ìwé tí ń fò, èyí tí gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, tí ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.”  Lẹ́yìn náà, ó wí fún mi pé: “Èyí ni ègún tí ń jáde lọ sórí gbogbo ilẹ̀ ayé,+ nítorí olúkúlùkù ẹni tí ń jalè,+ ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀ ní ìhà ìhín, ti lọ láìfara gba ìyà; olúkúlùkù ẹni tí ó sì ń búra,+ ní ìbámu pẹ̀lú rẹ̀ ní ìhà ọ̀hún,+ ti lọ láìfara gba ìyà.  ‘Mo ti mú kí ó jáde lọ,’ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ‘yóò sì wọnú ilé olè àti inú ilé ẹni tí ń búra ní orúkọ mi lọ́nà èké;+ yóò sì wọ̀ sí àárín ilé rẹ̀, yóò sì pa á run pátápátá àti ẹ̀là gẹdú rẹ̀ àti òkúta rẹ̀.’”+  Lẹ́yìn náà, áńgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ jáde lọ, ó sì wí fún mi pé: “Jọ̀wọ́, gbé ojú rẹ sókè, kí o sì rí ohun tí nǹkan tí ń jáde lọ yìí jẹ́.”  Nítorí náà, mo wí pé: “Kí ni?” Ẹ̀wẹ̀, ó wí pé: “Èyí ni òṣùwọ̀n eéfà tí ń jáde lọ.” Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Èyí ni ìrí ojú wọn ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”  Sì wò ó! ọmọrí bìrìkìtì tí a fi òjé ṣe ni a gbé sókè; obìnrin kan sì nìyí tí ó jókòó sáàárín òṣùwọ̀n eéfà náà.  Nítorí náà, ó wí pé: “Ìwà Burúkú ni èyí.” Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí jù ú padà sáàárín òṣùwọ̀n eéfà náà,+ lẹ́yìn èyí, ó fi òjé títẹ̀wọ̀n náà dé ẹnu rẹ̀.  Nígbà náà ni mo gbé ojú mi sókè, mo sì rí i, sì kíyè sí i, àwọn obìnrin méjì ń jáde bọ̀, ẹ̀fúùfù sì wà ní ìyẹ́ apá wọn. Wọ́n sì ní ìyẹ́ apá bí ìyẹ́ apá ẹyẹ àkọ̀. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, wọ́n gbé òṣùwọ̀n eéfà náà sókè láàárín ilẹ̀ ayé àti ọ̀run. 10  Nítorí náà, mo wí fún áńgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ pé: “Ibo ni wọ́n ń gbé òṣùwọ̀n eéfà náà lọ?” 11  Ẹ̀wẹ̀, ó wí fún mi pé: “Kí a lè kọ́+ ilé fún un ní ilẹ̀ Ṣínárì;+ wọn yóò sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, níbẹ̀ ni a ó sì fi lélẹ̀ sí ní àyè rẹ̀ tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé