Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sekaráyà 4:1-14

4  Áńgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì tẹ̀ síwájú láti padà wá, ó sì jí mi, bí ọkùnrin kan tí a jí lójú oorun rẹ̀.+  Lẹ́yìn náà, ó wí fún mi pé: “Kí ni o rí?”+ Nítorí náà, mo wí pé: “Mo ti rí i, sì wò ó! ọ̀pá fìtílà kan wà,+ gbogbo rẹ̀ jẹ́ wúrà, pẹ̀lú àwokòtò kan lórí rẹ̀. Àwọn fìtílà rẹ̀ méjèèje sì wà ní orí rẹ̀, àní méje;+ àwọn fìtílà tí ó sì wà ní orí rẹ̀ ní páìpù méje.  Àwọn igi ólífì méjì sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀,+ ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún àwokòtò náà àti ọ̀kan ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀.”  Nígbà náà ni mo dáhùn, mo sì wí fún áńgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀, pé: “Kí ni nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí, olúwa mi?”+  Nítorí náà, áńgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn, ó sì wí fún mi pé: “Ní ti tòótọ́, ìwọ kò ha mọ ohun tí nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí?” Ẹ̀wẹ̀, mo wí pé: “Rárá, olúwa mi.”+  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó dáhùn, ó sì wí fún mi pé: “Èyí ni ọ̀rọ̀ Jèhófà fún Serubábélì, pé, ‘“Kì í ṣe nípasẹ̀ ẹgbẹ́ ológun,+ tàbí nípasẹ̀ agbára,+ bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,”+ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.  Ta ni ọ́, ìwọ òkè ńlá títóbi?+ Ìwọ yóò di ilẹ̀ títẹ́jú pẹrẹsẹ níwájú Serubábélì.+ Dájúdájú, òun yóò sì mú olórí òkúta ìpìlẹ̀+ jáde wá. Kíkígbe+ sí i yóò wà, pé: “Ó mà lóòfà ẹwà o! Ó mà lóòfà ẹwà o!”’”+  Ọ̀rọ̀ Jèhófà sì ń bá a lọ láti tọ̀ mí wá, pé:  “Ọwọ́ Serubábélì fúnra rẹ̀ ti fi ìpìlẹ̀ ilé yìí lélẹ̀,+ ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀.+ Ìwọ yóò sì ní láti mọ̀ pé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun fúnra rẹ̀ ni ó rán mi sí yín.+ 10  Nítorí ta ni ó ti tẹ́ńbẹ́lú ọjọ́ àwọn ohun kékeré?+ Dájúdájú, wọn yóò sì yọ̀,+ wọn yóò sì rí okùn ìwọ̀n ní ọwọ́ Serubábélì. Àwọn méje yìí ni ojú Jèhófà.+ Wọ́n ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”+ 11  Mo sì bẹ̀rẹ̀ sí dáhùn, mo sì wí fún un pé: “Kí ni igi ólífì méjì yìí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ọ̀pá fìtílà àti ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀ túmọ̀ sí?”+ 12  Nígbà náà ni mo dáhùn ní ìgbà kejì, mo sì wí fún un pé: “Kí ni ìdìpọ̀ ẹ̀ka igi méjì igi ólífì náà tí ń da ohun olómi oníwúrà jáde láti inú ara wọn nípasẹ̀ túùbù oníwúrà méjì náà?” 13  Nítorí náà, ó wí fún mi pé: “Ìwọ kò ha mọ ohun tí nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí ní ti tòótọ́ bí?” Ẹ̀wẹ̀, mo wí pé: “Rárá, olúwa mi.”+ 14  Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ó wí pé: “Àwọn yìí ni àwọn ẹni àmì òróró méjì+ tí ń dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ Olúwa gbogbo ilẹ̀ ayé.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé