Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sekaráyà 3:1-10

3  Ó sì ń bá a lọ láti fi Jóṣúà+ àlùfáà àgbà hàn mi tí ó dúró níwájú áńgẹ́lì Jèhófà, Sátánì+ sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ láti takò ó.+  Nígbà náà ni [áńgẹ́lì+] Jèhófà wí fún Sátánì pé: “Jèhófà bá ọ wí lọ́nà mímúná, ìwọ Sátánì, bẹ́ẹ̀ ni, Jèhófà bá ọ wí lọ́nà mímúná,+ ẹni tí ó yan Jerúsálẹ́mù!+ Èyí ha kọ́ ni ìtì igi tí a fà yọ kúrò nínú iná?”+  Wàyí o, ní ti Jóṣúà, ó ṣẹlẹ̀ pé a fi ẹ̀wù+ tí a sọ di àìmọ́ wọ̀ ọ́, ó sì dúró níwájú áńgẹ́lì náà.  Lẹ́yìn náà, ó dáhùn, ó sì wí fún àwọn tí ó dúró níwájú rẹ̀ pé: “Ẹ bọ́ ẹ̀wù tí a sọ di àìmọ́ náà kúrò lára rẹ̀.” Ó sì ń bá a lọ láti wí fún un pé: “Wò ó! mo ti mú kí ìṣìnà rẹ kọjá kúrò lórí rẹ,+ a ó sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ ìgúnwà.”+  Látàrí ìyẹn, mo wí pé: “Jẹ́ kí wọ́n fi láwàní tí ó mọ́ sí orí rẹ̀.”+ Wọ́n sì ń bá a lọ láti fi láwàní tí ó mọ́ sí orí rẹ̀, wọ́n sì fi aṣọ wọ̀ ọ́; áńgẹ́lì Jèhófà sì dúró nítòsí.  Áńgẹ́lì Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ́rìí sí Jóṣúà, pé:  “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Bí ìwọ yóò bá máa rìn ní àwọn ọ̀nà mi, bí ìwọ yóò bá sì máa pa iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe mi mọ́,+ nígbà náà, ìwọ ni yóò ṣe ìdájọ́ ilé mi,+ ìwọ yóò sì pa àgbàlá mi mọ́ pẹ̀lú; dájúdájú, èmi yóò sì fún ọ ní àǹfààní láti rìn fàlàlà láàárín àwọn tí ó dúró nítòsí yìí.’  “‘Jọ̀wọ́, gbọ́, ìwọ Jóṣúà àlùfáà àgbà, ìwọ àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ tí ó jókòó níwájú rẹ, nítorí wọ́n jẹ́ àwọn ọkùnrin tí ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àmì àgbàyanu;+ nítorí kíyè sí i, èmi yóò mú ìránṣẹ́ mi+ tí í ṣe Ìrújáde,+ wọlé wá!  Nítorí, wò ó! òkúta+ tí mo fi síwájú Jóṣúà! Lórí òkúta náà ni ojú méje wà.+ Kíyè sí i, èmi yóò fín iṣẹ́ ọ̀nà fífín rẹ̀,’+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ‘èmi yóò sì mú ìṣìnà ilẹ̀ yẹn kúrò ní ọjọ́ kan ṣoṣo.’+ 10  “‘Ní ọjọ́ yẹn,’ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ‘Olúkúlùkù yín yóò pe ẹnì kejì rẹ̀, nígbà tí ẹ bá wà lábẹ́ àjàrà àti nígbà tí ẹ bá wà lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé