Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sekaráyà 14:1-21

14  “Wò ó! Ọjọ́ kan ń bọ̀, tí ó jẹ́ ti Jèhófà,+ ohun ìfiṣèjẹ rẹ ni a ó sì pín ní àárín rẹ.  Dájúdájú, èmi yóò sì kó gbogbo orílẹ̀-èdè jọ láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù fún ogun náà;+ a ó sì gba ìlú ńlá náà ní ti tòótọ́,+ a ó sì kó àwọn ilé ní ìkógun, àwọn obìnrin pàápàá ni a ó sì fipá bá lò pọ̀.+ Ìdajì ìlú ńlá náà yóò sì jáde lọ sí ìgbèkùn;+ ṣùgbọ́n ní ti àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára àwọn ènìyàn náà,+ a kì yóò ké wọn kúrò ní ìlú ńlá náà.+  “Dájúdájú, Jèhófà yóò sì jáde lọ láti bá àwọn orílẹ̀-èdè wọnnì jagun+ bí ti ọjọ́ ìjagun rẹ̀, ní ọjọ́ ìjà.+  Ní ọjọ́ yẹn, ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì dúró ní ti tòótọ́ lórí òkè ńlá igi ólífì, èyí tí ó wà ní iwájú Jerúsálẹ́mù, ní ìlà-oòrùn;+ òkè ńlá igi ólífì+ yóò sì là ní àárín,+ láti yíyọ oòrùn dé ìwọ̀-oòrùn. Àfonífojì ńlá kan yóò wà; ìdajì òkè ńlá náà ni a ó sì ṣí kúrò ní ti tòótọ́ lọ sí àríwá, àti ìdajì rẹ̀ sí gúúsù.  Dájúdájú, ẹ ó sì sá lọ sí àfonífojì àwọn òkè ńlá mi;+ nítorí àfonífojì àwọn òkè ńlá náà yóò dé iyàn-níyàn Ásélì. Ṣe ni ẹ óò sì sá lọ, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti sá lọ nítorí ìsẹ̀lẹ̀ ní àwọn ọjọ́ Ùsáyà ọba Júdà.+ Dájúdájú, Jèhófà Ọlọ́run mi yóò sì wá,+ gbogbo àwọn ẹni mímọ́ ń bẹ pẹ̀lú rẹ̀.+  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé kì yóò sí ìmọ́lẹ̀ iyebíye+—àwọn nǹkan yóò dì.+  Yóò sì di ọjọ́ kan tí a mọ̀ pé ó jẹ́ ti Jèhófà.+ Kì yóò jẹ́ ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò jẹ́ òru;+ yóò sì ṣẹlẹ̀ pé ní ìrọ̀lẹ́ yóò di ìmọ́lẹ̀.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé omi ààyè+ yóò jáde lọ láti Jerúsálẹ́mù,+ ìdajì rẹ̀ sí òkun ìhà ìlà-oòrùn+ àti ìdajì rẹ̀ sí òkun ìhà ìwọ̀-oòrùn.+ Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ní ìgbà òtútù ni yóò ṣẹlẹ̀.+  Jèhófà yóò sì di ọba lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.+ Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà yóò jẹ́ ọ̀kan,+ orúkọ rẹ̀ yóò sì jẹ́ ọ̀kan.+ 10  “Gbogbo ilẹ̀ ni a óò yí padà bí Árábà,+ láti Gébà+ dé Rímónì+ dé gúúsù Jerúsálẹ́mù; yóò dìde, yóò sì di ibi gbígbé ní àyè rẹ̀,+ láti Ẹnubodè Bẹ́ńjámínì+ dé iyàn-níyàn ibi Ẹnubodè Àkọ́kọ́, dé iyàn-níyàn Ẹnubodè Igun, àti láti Ilé Gogoro Hánánélì+ dé iyàn-níyàn ẹkù ìfúntí ọba. 11  Dájúdájú, àwọn ènìyàn yóò sì gbé inú rẹ̀; ìfòfindè fún ìparun kì yóò sì ṣẹlẹ̀ mọ́,+ a ó sì máa gbé Jerúsálẹ́mù nínú ààbò.+ 12  “Èyí ni yóò sì jẹ́ òjòjò àrànkálẹ̀ tí Jèhófà yóò fi kọlu gbogbo ènìyàn tí yóò ṣe iṣẹ́ ìsìn ológun ní ti tòótọ́ láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù:+ Ẹran ara ènìyàn yóò jẹrà dànù, bí ó tí dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀;+ ojú ènìyàn yóò jẹrà dànù nínú ojúhò wọn, ahọ́n ènìyàn yóò sì jẹrà dànù ní ẹnu rẹ̀. 13  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé ìdàrúdàpọ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà yóò di èyí tí ó tàn kálẹ̀ láàárín wọn;+ olúkúlùkù wọn ní ti gidi yóò sì rá ọwọ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mú, ọwọ́ rẹ̀ yóò sì wá láti gbéjà ko ọwọ́ alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀. 14  Júdà pàápàá yóò máa jagun pẹ̀lú ní Jerúsálẹ́mù; ọlà gbogbo orílẹ̀-èdè yí ká ni a ó sì kó jọ dájúdájú, wúrà àti fàdákà àti ẹ̀wù ní ọ̀pọ̀ yanturu.+ 15  “Báyìí sì ni òjòjò àrànkálẹ̀ ẹṣin, ìbaaka, ràkúnmí àti akọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti gbogbo onírúurú ẹran agbéléjẹ̀ tí ó bá wà ní àwọn ibùdó wọnnì yóò rí, bí òjòjò àrànkálẹ̀ yìí. 16  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ní ti olúkúlùkù ẹni tí ó ṣẹ́ kù nínú gbogbo orílẹ̀-èdè tí ń bọ̀ wá láti gbéjà ko Jerúsálẹ́mù,+ wọn yóò sì máa gòkè lọ pẹ̀lú láti ọdún dé ọdún+ láti tẹrí ba fún Ọba,+ Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ àti láti ṣe àjọyọ̀ àwọn àtíbàbà.+ 17  Yóò sì ṣẹlẹ̀ pé, ní ti ẹni náà nínú àwọn ìdílé+ orí ilẹ̀ ayé tí kò gòkè wá+ sí Jerúsálẹ́mù láti tẹrí ba fún Ọba, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, àní ọ̀yamùúmùú òjò kì yóò rọ̀ sórí wọn.+ 18  Bí ìdílé Íjíbítì pàápàá kò bá sì gòkè wá, tí kò sì wọlé ní ti gidi, kì yóò sí ìkankan lórí wọn pẹ̀lú. Òjòjò àrànkálẹ̀ náà yóò ṣẹlẹ̀, èyí tí Jèhófà fi kọlu àwọn orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti ṣe àjọyọ̀ àwọn àtíbàbà. 19  Èyí gan-an ni yóò jẹ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ Íjíbítì àti ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò gòkè wá láti ṣe àjọyọ̀ àwọn àtíbàbà.+ 20  “Ní ọjọ́ yẹn ‘Ìjẹ́mímọ́ jẹ́ ti Jèhófà!’+ yóò wà+ lára àwọn agogo ẹṣin. Àwọn ìkòkò ìse-oúnjẹ ẹlẹ́nu fífẹ̀+ inú ilé Jèhófà yóò sì dà bí àwọn àwokòtò+ níwájú pẹpẹ.+ 21  Gbogbo ìkòkò ìse-oúnjẹ ẹlẹ́nu fífẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù àti ní Júdà yóò sì di ohun mímọ́ tí ó jẹ́ ti Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, gbogbo àwọn tí ń rúbọ yóò sì wọlé wá láti gbà nínú wọn, wọn yóò sì se nǹkan nínú wọn.+ Kì yóò sì sí ọmọ Kénáánì+ mọ́ nínú ilé Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní ọjọ́ yẹn.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé