Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sekaráyà 12:1-14

12  Ọ̀rọ̀ ìkéde: “Ọ̀rọ̀ Jèhófà nípa Ísírẹ́lì,” ni àsọjáde Jèhófà, Ẹni tí ó na ọ̀run+ jáde, tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀,+ tí ó sì ṣẹ̀dá ẹ̀mí+ ènìyàn tí ń bẹ nínú rẹ̀.  “Kíyè sí i, èmi yóò sọ Jerúsálẹ́mù+ di àwokòtò tí ń fa ìtagọ̀ọ́gọ̀ọ́ fún gbogbo ènìyàn yí ká;+ òun yóò sì tún wá sàga ti Júdà, àní ti Jerúsálẹ́mù.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn+ pé èmi yóò sọ Jerúsálẹ́mù di òkúta+ ẹrù ìnira sí gbogbo ènìyàn. Gbogbo ẹni tí ń gbé e yóò fara bó yánnayànna láìkùnà; dájúdájú, a ó sì kó gbogbo orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé jọ lòdì sí i.+  Ní ọjọ́ yẹn,”+ ni àsọjáde Jèhófà, “Èmi yóò fi ìdàrúdàpọ̀-ọkàn kọlu gbogbo ẹṣin,+ èmi yóò sì fi ìṣiwèrè kọlu ẹni tí ó gùn ún;+ èmi yóò sì la ojú mi sára ilé Júdà,+ gbogbo ẹṣin àwọn ènìyàn náà ni èmi yóò sì fi ìpàdánù agbára ìríran kọlù.  Àwọn séríkí+ Júdà yóò sì wí ní ọkàn-àyà wọn pé, ‘Àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù jẹ́ okun fún mi nípa Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run wọn.’+  Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò ṣe àwọn séríkí Júdà bí ìkòkò tí a kóná sí láàárín igi+ àti bí ògùṣọ̀ oníná nínú ẹsẹ ọkà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gé,+ wọn yóò sì jẹ gbogbo ènìyàn run yíká-yíká ní ọwọ́ ọ̀tún àti ní òsì;+ síbẹ̀, a ó sì gbé inú Jerúsálẹ́mù ní àyè tirẹ̀, ní Jerúsálẹ́mù.+  “Dájúdájú, Jèhófà yóò sì kọ́kọ́ gba àgọ́ Júdà là, kí ẹwà ilé Dáfídì àti ẹwà àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù má bàa pọ̀ ju ti Júdà.  Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà yóò jẹ́ odi ìgbèjà yí ká àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù;+ ẹni tí ó sì ń kọsẹ̀ nínú wọn yóò sì dà bí Dáfídì ní ọjọ́ yẹn,+ ilé Dáfídì yóò sì dà bí Ọlọ́run,+ bí áńgẹ́lì Jèhófà níwájú wọn.+  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn pé èmi yóò wá ọ̀nà láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè tí ń wá ọ̀nà láti gbéjà kò Jerúsálẹ́mù rẹ́ ráúráú.+ 10  “Èmi yóò sì da ẹ̀mí ojú rere+ àti ti ìpàrọwà+ jáde sórí ilé Dáfídì àti sórí àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù, dájúdájú, wọn yóò sì wo Ẹni náà tí wọ́n gún ní àgúnyọ,+ wọn yóò sì pohùn réré ẹkún lórí Rẹ̀ dájúdájú bí ìpohùnréré ẹkún lórí ọmọkùnrin kan ṣoṣo; ìdárò kíkorò yóò sì wà lórí rẹ̀ bí ìgbà tí ìdárò kíkorò bá wà lórí àkọ́bí ọmọkùnrin.+ 11  Ní ọjọ́ yẹn, ìpohùnréré ẹkún ní Jerúsálẹ́mù yóò pọ̀ gidigidi, bí ìpohùnréré ẹkún Hadadirímónì ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àfonífojì Mẹ́gídò.+ 12  Dájúdájú, ilẹ̀ náà yóò sì pohùn réré ẹkún,+ ìdílé kọ̀ọ̀kan ní òun nìkan;+ ìdílé ti ilé Dáfídì ní òun nìkan, àti àwọn obìnrin wọn ní àwọn nìkan; ìdílé ti ilé Nátánì+ ní òun nìkan, àti àwọn obìnrin wọn ní àwọn nìkan; 13  ìdílé ti ilé Léfì+ ni òun nìkan, àti àwọn obìnrin wọn ní àwọn nìkan; ìdílé ti ọmọ Ṣíméì+ ní òun nìkan, àti àwọn obìnrin wọn ní àwọn nìkan; 14  gbogbo ìdílé tí ó ṣẹ́ kù, ìdílé kọ̀ọ̀kan ní òun nìkan, àti àwọn obìnrin wọn ní àwọn nìkan.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé