Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sekaráyà 10:1-12

10  “Ẹ béèrè fún òjò+ lọ́wọ́ Jèhófà ní àkókò òjò ìgbà ìrúwé,+ àní lọ́wọ́ Jèhófà tí ń ṣe àwọsánmà ìjì,+ tí ó sì ń fi eji wọwọ òjò fún wọn,+ tí ń fún olúkúlùkù ní ewéko inú pápá.+  Nítorí ère tẹ́ráfímù+ pàápàá ti sọ ohun abàmì; àwọn woṣẹ́woṣẹ́, ní tiwọn, ti rí ìran èké,+ àlá tí kò ní láárí sì ni wọ́n ń rọ́, lásán sì ni wọ́n ń gbìyànjú láti tuni nínú.+ Ìdí nìyẹn tí wọn yóò fi jáde lọ dájúdájú bí agbo ẹran;+ a óò ṣẹ́ wọn níṣẹ̀ẹ́, nítorí pé kò sí olùṣọ́ àgùntàn.+  “Ìbínú mi ti gbóná sí àwọn olùṣọ́ àgùntàn,+ èmi yóò sì béèrè fún ìjíhìn+ lọ́wọ́ àwọn aṣáájú oníwà-bí-ewúrẹ́;+ nítorí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti yí àfiyèsí rẹ̀ sọ́dọ̀ agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀,+ ilé Júdà, ó sì ṣe wọ́n bí ẹṣin+ rẹ̀ tí ó ní iyì nínú ìjà ogun.  Láti inú rẹ̀ ni gíríkì ọkùnrin ti wá,+ láti inú rẹ̀ ni olùṣàkóso aláfẹ̀yìntì ti wá,+ láti inú rẹ̀ ni ọrun ìjà ogun ti wá;+ láti inú rẹ̀ ni olúkúlùkù akóniṣiṣẹ́+ ti jáde lọ, gbogbo wọn lápapọ̀.  Wọn yóò sì dà bí àwọn ọkùnrin alágbára ńlá+ tí ń fi ẹsẹ̀ tẹ ẹrẹ̀ ojú pópó mọ́lẹ̀ nínú ìjà ogun.+ Wọn yóò sì ja ìjà ogun, nítorí Jèhófà wà pẹ̀lú wọn;+ àwọn olùgun ẹṣin yóò sì ní ìrírí ìtìjú.+  Dájúdájú, èmi yóò sì sọ ilé Júdà di alágbára gíga, èmi yóò sì gba ilé Jósẹ́fù là.+ Èmi yóò sì fún wọn ní ibùgbé, nítorí èmi yóò fi àánú hàn sí wọn;+ wọn yóò sì dà bí àwọn tí èmi kò ta nù;+ nítorí èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn, èmi yóò sì dá wọn lóhùn.+  Àwọn ti Éfúráímù yóò sì dà bí ọkùnrin alágbára ńlá,+ ọkàn-àyà wọn yóò sì máa yọ̀ bí ẹni pé nítorí wáìnì.+ Àwọn ọmọ wọn yóò sì rí i, wọn yóò sì máa yọ̀ dájúdájú;+ ọkàn-àyà wọn yóò kún fún ìdùnnú nínú Jèhófà.+  “‘Èmi yóò súfèé sí wọn,+ èmi yóò sì kó wọn jọpọ̀; nítorí èmi yóò tún wọn rà padà dájúdájú,+ wọn yóò sì di púpọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó ti di púpọ̀.+  Èmi yóò sì tú wọn ká bí irúgbìn sáàárín àwọn ènìyàn,+ wọn yóò sì rántí mi láti ibi jíjìnnà;+ wọn yóò sì sọ jí pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, wọn yóò sì padà.+ 10  Èmi yóò sì mú wọn padà wá láti ilẹ̀ Íjíbítì;+ èmi yóò sì kó wọn jọpọ̀ láti Ásíríà;+ èmi yóò mú wọn wá sí ilẹ̀ Gílíádì+ àti Lẹ́bánónì, a kì yóò sì rí àyè fún wọn.+ 11  Òun yóò sì la òkun kọjá pẹ̀lú wàhálà;+ òun yóò sì ṣá ìgbì balẹ̀ nínú òkun,+ gbogbo ibú Náílì yóò sì gbẹ táútáú.+ A ó sì rẹ ìyangàn Ásíríà sílẹ̀,+ ọ̀pá aládé+ Íjíbítì gan-an yóò sì lọ.+ 12  Èmi yóò sì sọ wọ́n di alágbára gíga nínú Jèhófà,+ wọn yóò sì rìn káàkiri ní orúkọ rẹ̀,’+ ni àsọjáde Jèhófà.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé