Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sekaráyà 1:1-21

1  Ní oṣù kẹjọ, ní ọdún kejì Dáríúsì,+ ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Sekaráyà+ ọmọkùnrin Berekáyà ọmọkùnrin Ídò+ wòlíì wá, pé:  “Ìkannú Jèhófà ru sí àwọn baba yín—ó ru gidigidi.+  “Ìwọ yóò sì wí fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “‘Ẹ padà sọ́dọ̀ mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, ‘èmi yóò sì padà sọ́dọ̀ yín,’+ ni Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí.”’  “‘Ẹ má dà bí àwọn baba yín+ tí àwọn wòlíì àtijọ́ pè,+ wí pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Ẹ jọ̀wọ́, ẹ padà kúrò ní ọ̀nà búburú yín àti kúrò nínú ìbálò búburú yín.’”’+ “‘Ṣùgbọ́n wọn kò fetí sílẹ̀, wọn kò sì fiyè sí mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà.  “‘Ní ti àwọn baba yín, ibo ni wọ́n wà?+ Àti ní ti àwọn wòlíì,+ wọ́n ha ń bá a lọ láti wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin?  Bí ó ti wù kí ó rí, ní ti àwọn ọ̀rọ̀ mi àti àwọn ìlànà mi tí mo pa láṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì,+ wọn kò ha lé àwọn baba yín bá?’+ Nítorí náà, wọ́n padà, wọ́n sì wí pé: ‘Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ní lọ́kàn láti ṣe sí wa,+ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀nà wa àti gẹ́gẹ́ bí àwọn ìbálò wa, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe sí wa.’”+  Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kọkànlá, èyíinì ni, oṣù Ṣébátì, ní ọdún kejì Dáríúsì,+ ọ̀rọ̀ Jèhófà tọ Sekaráyà+ ọmọkùnrin Berekáyà ọmọkùnrin Ídò+ wòlíì wá, pé:  “Mo rí i ní òru, sì wò ó! ọkùnrin kan+ tí ó gun ẹṣin pupa,+ ó sì dúró jẹ́ẹ́ láàárín àwọn igi mátílì+ tí ó wà ní ibi jíjìn; lẹ́yìn rẹ̀ sì ni àwọn ẹṣin pupa, pupa fòò, àti funfun wà.”+  Nítorí náà, mo wí pé: “Àwọn wo nìyí, olúwa mi?”+ Látàrí ìyẹn, áńgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ wí+ fún mi pé: “Èmi fúnra mi yóò fi ẹni tí àwọn yìí gan-an jẹ́ hàn ọ́.” 10  Lẹ́yìn náà, ọkùnrin tí ó dúró jẹ́ẹ́ láàárín àwọn igi mátílì náà dáhùn, ó sì wí pé: “Ìwọ̀nyí ni àwọn tí Jèhófà rán jáde láti rìn káàkiri ní ilẹ̀ ayé.”+ 11  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dá áńgẹ́lì Jèhófà tí ó dúró láàárín àwọn igi mátílì náà lóhùn, wọ́n sì wí pé: “A ti rìn káàkiri ní ilẹ̀ ayé,+ sì wò ó! gbogbo ilẹ̀ ayé jókòó jẹ́ẹ́, kò sì ní ìyọlẹ́nu kankan.”+ 12  Nítorí náà, áńgẹ́lì Jèhófà dáhùn, ó sì wí pé: “Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ fúnra rẹ kì yóò fi àánú hàn sí Jerúsálẹ́mù àti sí àwọn ìlú ńlá Júdà,+ tí o ti dá lẹ́bi fún àádọ́rin ọdún wọ̀nyí?”+ 13  Jèhófà sì tẹ̀ síwájú láti fi ọ̀rọ̀ rere, ọ̀rọ̀ tí ń tuni nínú dá áńgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ lóhùn;+ 14  áńgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì ń bá a lọ láti wí fún mi pé: “Ké jáde, pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Mo ti fi owú ńláǹlà jowú fún Jerúsálẹ́mù àti fún Síónì.+ 15  Pẹ̀lú ìkannú ńláǹlà ni ìkannú mi fi ru sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní ìdẹ̀rùn;+ nítorí pé èmi, ní tèmi, ìkannú mi ru ní ìwọ̀n díẹ̀,+ ṣùgbọ́n àwọn, ní tiwọn, ṣe ìrànwọ́ síhà ìyọnu àjálù.”’+ 16  “Nítorí náà, èyí ni ohun tí Jèhófà wí, ‘“Dájúdájú, èmi yóò padà sọ́dọ̀ Jerúsálẹ́mù pẹ̀lú àánú.+ Ilé tèmi ni a óò kọ́ sínú rẹ̀,”+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, “àní okùn ìdiwọ̀n ni a ó nà sórí Jerúsálẹ́mù.”’+ 17  “Tún ké jáde, pé, ‘Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí: “Àwọn ìlú ńlá mi yóò ṣì kún àkúnwọ́sílẹ̀ pẹ̀lú ìwà rere;+ dájúdájú, Jèhófà yóò ṣì kẹ́dùn nítorí Síónì,+ yóò yan Jerúsálẹ́mù ní ti gidi.”’”+ 18  Mo sì tẹ̀ síwájú láti gbé ojú mi sókè, mo sì rí i; sì wò ó! ìwo mẹ́rin ni ó wà.+ 19  Nítorí náà, mo wí fún áńgẹ́lì tí ń bá mi sọ̀rọ̀ pé: “Kí ni ìwọ̀nyí?” Ẹ̀wẹ̀, ó wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ìwo tí ó fọ́n Júdà,+ Ísírẹ́lì,+ àti Jerúsálẹ́mù+ ká.” 20  Síwájú sí i, Jèhófà fi àwọn oníṣẹ́ ọnà mẹ́rin hàn mí. 21  Látàrí ìyẹn, mo wí pé: “Kí ni àwọn yìí ń bọ̀ wá ṣe?” Ó sì ń bá a lọ láti wí pé: “Ìwọ̀nyí ni àwọn ìwo+ tí ó fọ́n Júdà ká tó bẹ́ẹ̀ tí kò fi sí ẹnì kankan tí ó gbé orí sókè; àwọn kejì wọ̀nyí yóò sì wá láti mú kí wọ́n wárìrì, láti mú ìrẹ̀sílẹ̀ bá ìwo àwọn orílẹ̀-èdè tí ń gbé ìwo sókè sí ilẹ̀ Júdà, láti fọ́n ọn ká.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé