Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sefanáyà 3:1-20

3  Ègbé ni fún ẹni tí ń ṣọ̀tẹ̀, tí ó sì ń sọ ara rẹ̀ di eléèérí, ìlú ńlá tí ń nini lára!+  Kò fetí sí ohùn;+ kò tẹ́wọ́ gba ìbáwí.+ Kò ní ìgbẹ́kẹ̀lé+ nínú Jèhófà. Kò sún mọ́+ Ọlọ́run rẹ̀.  Àwọn ọmọ aládé rẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ̀ jẹ́ kìnnìún+ tí ń ké ramúramù. Àwọn onídàájọ́ rẹ̀ jẹ́ ìkookò ìrọ̀lẹ́ tí kò gé egungun jẹ títí di òwúrọ̀.+  Àwọn wòlíì rẹ̀ jẹ́ aláfojúdi, wọ́n jẹ́ aládàkàdekè+ ènìyàn. Àwọn àlùfáà rẹ̀ alára sọ ohun tí ó jẹ́ mímọ́ di aláìmọ́; wọ́n ṣe ohun àìtọ́ sí òfin.+  Jèhófà jẹ́ olódodo ní àárín rẹ̀;+ òun kì yóò ṣe àìṣòdodo rárá.+ Òròòwúrọ̀ ni ó ń fúnni ní ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀.+ Ní ojúmọmọ, kò lè ṣe kí ó má sí.+ Ṣùgbọ́n aláìṣòdodo kò mọ ìtìjú.+  “Mo ké àwọn orílẹ̀-èdè kúrò; àwọn ilé gogoro wọn tí ó wà ní igun odi ni a sọ di ahoro. Mo pa àwọn ojú pópó wọn run di ahoro, tí kò fi sí ẹni tí ń gbà á kọjá. Àwọn ìlú ńlá wọn ni a sọ di ahoro, tí kò fi sí ènìyàn kankan, tí kò fi sí olùgbé kankan.+  Mo wí pé, ‘Dájúdájú, ìwọ yóò bẹ̀rù mi; ìwọ yóò tẹ́wọ́ gba ìbáwí’;+ kí a má bàa ké ibùgbé rẹ̀ kúrò+—gbogbo ìyẹn ni èmi yóò pè é wá jíhìn fún.+ Lóòótọ́, wọ́n gbé ìgbésẹ̀ kánmọ́kánmọ́ ní sísọ gbogbo ìbánilò wọn di èyí tí ń pani run.+  “‘Nítorí náà, ẹ máa wà ní ìfojúsọ́nà fún mi,’+ ni àsọjáde Jèhófà, ‘títí di ọjọ́ tí èmi yóò dìde sí ẹrù àkótogunbọ̀,+ nítorí ìpinnu ìdájọ́ mi ni láti kó àwọn orílẹ̀-èdè+ jọ, kí n kó àwọn ìjọba jọpọ̀, kí n lè da ìdálẹ́bi+ tí ó ti ọ̀dọ̀ mi wá jáde sórí wọn, gbogbo ìbínú jíjófòfò mi; nítorí nípa iná ìtara mi, gbogbo ilẹ̀ ayé ni a ó jẹ run.+  Nítorí pé nígbà náà ni èmi yóò fún àwọn ènìyàn ní ìyípadà sí èdè+ mímọ́ gaara, kí gbogbo wọn lè máa pe orúkọ Jèhófà,+ kí wọ́n lè máa sìn ín ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́.’+ 10  “Láti ẹkùn ilẹ̀ àwọn odò Etiópíà ni àwọn tí ń pàrọwà sí mi, èyíinì ni, ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi tí a tú ká, yóò ti mú ẹ̀bùn wá fún mi.+ 11  Ní ọjọ́ yẹn, ojú kì yóò tì ọ́ nítorí gbogbo ìbánilò rẹ èyí tí o fi ré ìlànà mi kọjá,+ nítorí pé nígbà náà ni èmi yóò mú àwọn tìrẹ tí ń fi ìrera yọ ayọ̀ ńláǹlà kúrò ní àárín rẹ;+ ìwọ kì yóò sì tún jẹ́ onírera mọ́ ní òkè ńlá+ mímọ́ mi. 12  Dájúdájú, èmi yóò sì jẹ́ kí àwọn onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni rírẹlẹ̀+ ṣẹ́ kù sí àárín rẹ, wọn yóò sì sá di orúkọ Jèhófà+ ní ti tòótọ́. 13  Ní ti àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára Ísírẹ́lì,+ wọn kì yóò ṣe àìṣòdodo,+ tàbí kí wọ́n pa irọ́,+ bẹ́ẹ̀ ni a kì yóò rí ahọ́n àgálámàṣà+ ní ẹnu wọn; nítorí àwọn fúnra wọn yóò jẹun, wọn yóò sì nà gbalaja+ ní ti tòótọ́, kò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”+ 14  Fi ìdùnnú ké jáde, ìwọ ọmọbìnrin Síónì! Bú jáde nínú ìmóríyá+ gágá, ìwọ Ísírẹ́lì! Máa yọ̀, kí o sì fi gbogbo ọkàn-àyà yọ ayọ̀ ńláǹlà, ìwọ ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù!+ 15  Jèhófà ti mú ìdájọ́ wọnnì kúrò lórí rẹ.+ Ó ti lé ọ̀tá rẹ+ padà. Ọba Ísírẹ́lì, Jèhófà, wà ní àárín rẹ.+ Ìwọ kì yóò tún bẹ̀rù ìyọnu àjálù mọ́.+ 16  Ní ọjọ́ yẹn, a óò wí fún Jerúsálẹ́mù pé: “Má fòyà, ìwọ Síónì.+ Kí ọwọ́ rẹ má rọ jọwọrọ.+ 17  Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà ní àárín rẹ. Bí Ẹni tí ó ní agbára ńlá, òun yóò gbà là.+ Òun yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí rẹ pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀.+ Òun yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́ nínú ìfẹ́ rẹ̀. Òun yóò kún fún ìdùnnú pẹ̀lú igbe ayọ̀ lórí rẹ. 18  “Àwọn tí ẹ̀dùn ọkàn kọlù+ nítorí àìsí níbẹ̀ ní àkókò àjọyọ̀ rẹ ni èmi yóò kó jọpọ̀+ dájúdájú; ó ṣẹlẹ̀ pé wọn kò sí lọ́dọ̀ rẹ, nítorí ríru ẹ̀gàn ní tìtorí+ rẹ̀. 19  Kíyè sí i, èmi yóò gbé ìgbésẹ̀ láti dojú ìjà kọ gbogbo àwọn tí ń ṣẹ́ ọ níṣẹ̀ẹ́, ní àkókò yẹn;+ èmi yóò sì gba ẹni tí ń tiro+ là, èmi yóò sì kó ẹni tí a fọ́n ká jọpọ̀.+ Dájúdájú, èmi yóò sì gbé wọn kalẹ̀ bí ìyìn àti bí orúkọ ní gbogbo ilẹ̀ ìtìjú wọn. 20  Ní àkókò yẹn, èmi yóò mú yín wọlé, àní ní àkókò tí èmi yóò kó yín jọpọ̀. Nítorí tí èmi yóò ṣe yín ní orúkọ àti ìyìn láàárín gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ ayé, nígbà tí mo bá kó àwọn òǹdè yín jọ padà ní ojú yín,” ni Jèhófà wí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé