Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sefanáyà 2:1-15

2  Ẹ kó ara yín jọpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni, ṣe ìkójọ+ náà, ìwọ orílẹ̀-èdè tí kò rẹ̀wẹ̀sì nínú ìtìjú.+  Kí ìlànà àgbékalẹ̀ náà tó bí ohunkóhun,+ kí ọjọ́ náà tó kọjá lọ bí ìyàngbò, kí ìbínú jíjófòfò Jèhófà+ tó wá sórí yín, kí ọjọ́ ìbínú+ Jèhófà tó wá sórí yín,  ẹ wá Jèhófà,+ gbogbo ẹ̀yin ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé,+ tí ń fi ìpinnu ìdájọ́ Tirẹ̀ ṣe ìwà hù. Ẹ wá òdodo,+ ẹ wá ọkàn-tútù.+ Bóyá+ a lè pa yín mọ́ ní ọjọ́ ìbínú+ Jèhófà.  Nítorí, ní ti Gásà, yóò di ìlú ńlá ti a pa tì;+ Áṣíkẹ́lónì yóò sì di ahoro.+ Ní ti Áṣídódì,+ ọ̀sán ganrínganrín ni wọn yóò lé e jáde;+ àti ní ti Ékírónì, a ó fà á tu.+  “Ègbé ni fún àwọn tí ń gbé ẹkùn ilẹ̀ òkun, orílẹ̀-èdè àwọn Kérétì!+ Ọ̀rọ̀ Jèhófà wà lòdì sí yín. Ìwọ Kénáánì, ilẹ̀ àwọn Filísínì, dájúdájú, èmi yóò pa ọ́ run pẹ̀lú, tí kì yóò fi sí olùgbé kankan.+  Ẹkùn ilẹ̀ òkun yóò sì di ilẹ̀ ìjẹko,+ tí ó ní àwọn kànga fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn àti àwọn ọgbà ẹran tí a fi òkúta ṣe fún àwọn àgùntàn.  Yóò sì di ẹkùn ilẹ̀ fún àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára ilé Júdà.+ Orí wọn ni wọn yóò ti máa jẹun. Inú àwọn ilé Áṣíkẹ́lónì ni wọn yóò nà gbalaja sí ní ìrọ̀lẹ́. Nítorí Jèhófà Ọlọ́run wọn yóò yí àfiyèsí rẹ̀ sí wọn,+ yóò sì kó àwọn òǹdè nínú wọn jọ padà dájúdájú.”+  “Mo ti gbọ́ ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ Móábù+ àti àwọn ọ̀rọ̀ èébú àwọn ọmọ Ámónì,+ èyí tí wọ́n ti fi gan àwọn ènìyàn mi, tí wọ́n sì ń bá a nìṣó ní gbígbé àgbéré ńláǹlà sí ìpínlẹ̀ wọn.  Nítorí náà, bí mo ti ń bẹ láàyè,”+ ni àsọjáde Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, “Móábù alára yóò dà bí Sódómù+ gẹ́lẹ́, àti àwọn ọmọ Ámónì+ bí Gòmórà, ibi tí èsìsì bò, àti kòtò iyọ̀, àti ahoro, àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú àwọn ènìyàn mi yóò piyẹ́ wọn, àṣẹ́kù nínú orílẹ̀-èdè tèmi yóò sì gbà wọ́n.+ 10  Èyí ni ohun tí wọn yóò gbà dípò ìgbéraga+ wọn, nítorí pé wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì ń bá a nìṣó ní gbígbé àgbéré ńláǹlà sí àwọn ènìyàn Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.+ 11  Jèhófà yóò jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù sí wọn;+ nítorí òun yóò mú kí gbogbo àwọn ọlọ́run ilẹ̀ ayé+ rù hangogo, àwọn ènìyàn yóò sì tẹrí ba fún un,+ olúkúlùkù láti ipò rẹ̀, gbogbo erékùṣù àwọn orílẹ̀-èdè.+ 12  “Ẹ̀yin pẹ̀lú, ẹ̀yin ará Etiópíà,+ ẹ̀yin alára yóò jẹ́ àwọn ènìyàn tí a fi idà+ mi pa. 13  “Òun yóò sì na ọwọ́ rẹ̀ jáde síhà àríwá, yóò sì pa Ásíríà+ run. Yóò sì sọ Nínéfè di ahoro,+ ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi bí aginjù. 14  Àwọn agbo ẹran ọ̀sìn yóò sì nà gbalaja sí àárín rẹ̀ dájúdájú, gbogbo àwọn ẹranko ìgbẹ́ orílẹ̀-èdè.+ Ẹyẹ òfú àti òòrẹ̀+ yóò sùn mọ́jú láàárín àwọn ọpọ́n+ orí ọwọ̀n rẹ̀ gan-an. Ohùn kan yóò máa kọrin lójú fèrèsé. Ìparundahoro yóò wà ní ibi àbáwọlé; nítorí pé dájúdájú, òun yóò tú pátákó ìsàlẹ̀ ògiri+ pàápàá sí borokoto. 15  Èyí ni ìlú ńlá tí ó kún fún ayọ̀ ńláǹlà tí ó jókòó ní ààbò,+ tí ó ń wí nínú ọkàn-àyà rẹ̀ pé, ‘Èmi ni, kò sì sí ẹlòmíràn.’+ Ẹ wo bí ó ṣe di ohun ìyàlẹ́nu tó, ibi tí àwọn ẹranko ìgbẹ́ ń nà gbalaja sí! Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń gba ọ̀dọ̀ rẹ̀ kọjá yóò súfèé; yóò gbọn ọwọ́ rẹ̀.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé