Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sefanáyà 1:1-18

1  Ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó tọ Sefanáyà ọmọ Kúúṣì, ọmọ Gẹdaláyà, ọmọ Amaráyà, ọmọ Hesekáyà wá ní àwọn ọjọ́ Jòsáyà+ ọmọ Ámọ́nì+ ọba Júdà:  “Láìkùnà, èmi yóò pa ohun gbogbo rẹ́ kúrò lórí ilẹ̀,” ni àsọjáde Jèhófà.+  “Èmi yóò pa ará ayé àti ẹranko+ rẹ́. Èmi yóò pa ẹ̀dá tí ń fò ní ojú ọ̀run àti àwọn ẹja òkun+ rẹ́, àti àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹni burúkú;+ dájúdájú, èmi yóò sì ké aráyé kúrò lórí ilẹ̀,”+ ni àsọjáde Jèhófà.  “Dájúdájú, èmi yóò sì na ọwọ́ mi jáde lòdì sí Júdà àti lòdì sí gbogbo àwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù,+ èmi yóò sì ké àwọn tí ó ṣẹ́ kù nínú Báálì+ kúrò ní ibí yìí, àti orúkọ àwọn àlùfáà ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àlùfáà,+  àti àwọn tí ń tẹrí ba fún ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run+ lórí àwọn òrùlé, àti àwọn tí ń tẹrí ba,+ tí ń búra fún Jèhófà,+ tí ó sì ń fi Málíkámù+ búra;  àti àwọn tí ń fà sẹ́yìn kúrò ní títọ Jèhófà+ lẹ́yìn, tí wọn kò sì wá Jèhófà, tí wọn kò sì ṣe ìwádìí nípa rẹ̀.”+  Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ;+ nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé,+ nítorí Jèhófà ti pèsè ẹbọ+ sílẹ̀; ó ti sọ àwọn tí ó ké sí di mímọ́.+  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ ẹbọ Jèhófà pé èmi yóò fún àwọn ọmọ aládé ní àfiyèsí dájúdájú, èmi yóò sì fún àwọn ọmọ ọba,+ àti gbogbo àwọn tí ń wọ aṣọ ilẹ̀ òkèèrè+ ní àfiyèsí.  Dájúdájú, èmi yóò sì fún olúkúlùkù ẹni tí ń gun pèpéle ní àfiyèsí ní ọjọ́ yẹn, àwọn tí ń fi ìwà ipá àti ẹ̀tàn+ kún ilé ọ̀gá wọn. 10  Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ yẹn,” ni àsọjáde Jèhófà, “ìró igbe ẹkún yóò ti Ẹnubodè Ẹja+ wá, àti híhu láti ìhà kejì,+ àti ìfọ́yángá ńláǹlà láti àwọn òkè kéékèèké.+ 11  Ẹ hu,+ ẹ̀yin olùgbé Mákítẹ́ṣì, nítorí gbogbo àwọn ènìyàn tí ó jẹ́ oníṣòwò ni a ti pa lẹ́nu mọ́;+ gbogbo àwọn tí ń wọn fàdákà ni a ti ké kúrò. 12  “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní àkókò yẹn pé èmi yóò fi fìtílà+ wá inú Jerúsálẹ́mù lẹ́sọ̀lẹsọ̀ dájúdájú, èmi yóò sì fún àwọn ènìyàn tí ń dì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀+ wọn ní àfiyèsí, tí wọ́n sì ń sọ ní ọkàn-àyà wọn pé, ‘Jèhófà kì yóò ṣe rere, kì yóò sì ṣe búburú.’+ 13  Ọlà wọn yóò sì wá jẹ́ fún ìkógun àti ilé wọn fún ahoro.+ Wọn yóò sì kọ́ ilé, ṣùgbọ́n wọn kì yóò gbé inú wọn;+ wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n wọn kì yóò mu wáìnì wọn.+ 14  “Ọjọ́ ńlá+ Jèhófà sún mọ́lé.+ Ó sún mọ́lé, ìyára kánkán rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.+ Ìró ọjọ́ Jèhófà korò.+ Alágbára ńlá ọkùnrin yóò figbe ta+ níbẹ̀. 15  Ọjọ́ yẹn jẹ́ ọjọ́ ìbínú kíkan, ọjọ́ wàhálà àti làásìgbò,+ ọjọ́ ìjì àti ìsọdahoro, ọjọ́ òkùnkùn àti ìṣúdùdù,+ ọjọ́ àwọsánmà àti ìṣúdùdù tí ó nípọn, 16  ọjọ́ ìwo àti ti àmì àfiyèsí+ oníròó ìdágìrì, lòdì sí àwọn ìlú ńlá olódi àti lòdì sí àwọn ilé gogoro+ tí ó wà ní igun odi. 17  Dájúdájú, èmi yóò sì fa wàhálà bá aráyé, wọn yóò sì máa rìn bí afọ́jú;+ nítorí pé Jèhófà ni wọ́n ti ṣẹ̀+ sí. Ẹ̀jẹ̀ wọn ni a ó sì tú jáde bí ekuru+ ní ti tòótọ́, àti ìwọ́rọ́kù wọn bí imí.+ 18  Fàdákà wọn tàbí wúrà wọn kì yóò lè dá wọn nídè ní ọjọ́ ìbínú kíkan+ Jèhófà; ṣùgbọ́n nípa iná ìtara rẹ̀, gbogbo ilẹ̀ ayé ni a ó jẹ run,+ nítorí tí yóò mú ìparun pátápátá, ọ̀kan tí ń jáni láyà ní tòótọ́, wá bá gbogbo àwọn olùgbé ilẹ̀ ayé.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé