Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 99:1-9

99  Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba.+ Kí ṣìbáṣìbo bá àwọn ènìyàn.+ Ó jókòó lórí àwọn kérúbù.+ Kí ilẹ̀ ayé gbọ̀n pẹ̀pẹ̀.+   Jèhófà tóbi ní Síónì,+ Ó sì ga ju gbogbo ènìyàn lọ.+   Kí wọ́n gbé orúkọ rẹ lárugẹ.+ Títóbi àti amúnikún-fún-ẹ̀rù ni, mímọ́ ni.+   Àti pé nínú okun ọba, òun nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́.+ Ìwọ tìkára rẹ ti fìdí ìdúróṣánṣán múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+ Ìdájọ́ àti òdodo ni ìwọ tìkára rẹ ti fi múlẹ̀ ní Jékọ́bù.+   Ẹ gbé Jèhófà Ọlọ́run wa ga,+ kí ẹ sì tẹrí ba níbi àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀;+ Ẹni mímọ́ ni.+   Mósè àti Áárónì wà lára àwọn àlùfáà rẹ̀,+ Sámúẹ́lì sì wà lára àwọn tí ń ké pe orúkọ rẹ̀.+ Wọ́n ń pe Jèhófà, òun tìkára rẹ̀ sì ń dá wọn lóhùn.+   Ó ń bá a lọ ní bíbá wọn sọ̀rọ̀ nínú ọwọ̀n àwọsánmà.+ Wọ́n pa àwọn ìránnilétí rẹ̀ àti ìlànà tí ó fún wọn mọ́.+   Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run wa, ìwọ tìkára rẹ dá wọn lóhùn.+ Ọlọ́run tí ń dárí jini ni ìwọ jẹ́ sí wọn,+ Ìwọ sì ń gbẹ̀san àwọn ohun olókìkí burúkú tí wọ́n ṣe.+   Ẹ gbé Jèhófà Ọlọ́run wa ga,+ Kí ẹ sì tẹrí ba níbi òkè ńlá mímọ́ rẹ̀.+ Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé