Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 98:1-9

Orin atunilára. 98  Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà,+ Nítorí pé àgbàyanu ni àwọn ohun tí ó ṣe.+ Ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀, àní apá mímọ́ rẹ̀, ti jèrè ìgbàlà fún un.+   Jèhófà ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mímọ̀;+ Ó ti ṣí òdodo rẹ̀ payá ní ojú àwọn orílẹ̀-èdè.+   Ó ti rántí inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ àti ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí ilé Ísírẹ́lì.+ Gbogbo òpin ilẹ̀ ayé ti rí ìgbàlà láti ọwọ́ Ọlọ́run wa.+   Ẹ kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun sí Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé.+ Ẹ tújú ká, kí ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, kí ẹ sì kọ orin atunilára.+   Ẹ fi háàpù kọ orin atunilára sí Jèhófà,+ Pẹ̀lú háàpù àti ohùn orin atunilára.+   Pẹ̀lú kàkàkí àti ìró ìwo+ Ẹ kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun níwájú Ọba náà, Jèhófà.   Kí òkun sán ààrá àti ohun tí ó kún inú rẹ̀,+ Ilẹ̀ eléso àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.+   Kí àwọn odò pàápàá pàtẹ́wọ́; Àní kí gbogbo àwọn òkè ńlá lápapọ̀ fi ìdùnnú ké jáde+   Níwájú Jèhófà, nítorí pé ó ti wá láti ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé.+ Òun yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ eléso,+ Yóò sì fi ìdúróṣánṣán ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé