Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 97:1-12

97  Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba!+ Kí ilẹ̀ ayé kún fún ìdùnnú.+Kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù máa yọ̀.+   Àwọsánmà àti ìṣúdùdù nínípọn yí i ká;+Òdodo àti ìdájọ́ ni ibi àfìdímúlẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.+   Àní iná kan lọ níwájú rẹ̀,+Ó sì jẹ àwọn elénìní rẹ̀ run yí ká.+   Mànàmáná rẹ̀ mú ilẹ̀ eléso mọ́lẹ̀ kedere;+Ilẹ̀ ayé rí i, ó sì wá wà nínú ìrora mímúná.+   Àní àwọn òkè ńlá bẹ̀rẹ̀ sí yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda ní tìtorí Jèhófà,+Ní tìtorí Olúwa gbogbo ilẹ̀ ayé.+   Ọ̀run ti sọ̀rọ̀ òdodo rẹ̀,+Gbogbo ènìyàn sì ti rí ògo rẹ̀.+   Kí ojú ti gbogbo àwọn tí ń sin ère gbígbẹ́,+Àwọn tí ń fi àwọn ọlọ́run tí kò ní láárí ṣògo.+Ẹ tẹrí ba fún un, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run.+   Síónì gbọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀,+Àwọn àrọko Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí kún fún ìdùnnú+Nítorí àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ, Jèhófà.+   Nítorí pé ìwọ, Jèhófà, ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé;+Ìwọ ròkè gan-an dé ipò gíga lókè gbogbo àwọn ọlọ́run yòókù.+ 10  Ẹ̀yin tí ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà,+ ẹ kórìíra ohun búburú.+Ó ń ṣọ́ ọkàn àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀;+Ó ń dá wọn nídè kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni burúkú.+ 11  Ìmọ́lẹ̀ ti kọ mànà fún olódodo,+Àti ayọ̀ yíyọ̀ àní fún àwọn adúróṣánṣán ní ọkàn-àyà.+ 12  Ẹ máa yọ̀ nínú Jèhófà, ẹ̀yin olódodo,+Kí ẹ sì máa fi ọpẹ́ fún ìrántí mímọ́ rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé