Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 96:1-13

96  Ẹ kọ orin tuntun sí Jèhófà.+ Ẹ kọrin sí Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé.+   Ẹ kọrin sí Jèhófà, ẹ fi ìbùkún fún orúkọ rẹ̀.+ Ẹ máa sọ ìhìn rere ìgbàlà rẹ̀ láti ọjọ́ dé ọjọ́.+   Ẹ máa polongo ògo rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,+ Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ láàárín gbogbo ènìyàn.+   Nítorí pé Jèhófà tóbi lọ́lá,+ ó sì yẹ fún ìyìn gidigidi. Ó jẹ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ju gbogbo ọlọ́run yòókù lọ.+   Nítorí gbogbo ọlọ́run àwọn ènìyàn jẹ́ àwọn ọlọrun tí kò ní láárí;+ Ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, òun ni ó ṣe ọ̀run pàápàá.+   Iyì àti ọlá ńlá ń bẹ níwájú rẹ̀;+ Okun àti ẹwà ń bẹ nínú ibùjọsìn rẹ̀.+   Ẹ gbé e fún Jèhófà, ẹ̀yin ìdílé àwọn ènìyàn,+ Ẹ gbé ògo àti okun fún Jèhófà.+   Ẹ gbé ògo tí ó jẹ́ ti orúkọ Jèhófà fún un;+ Ẹ gbé ẹ̀bùn, kí ẹ sì wá sínú àwọn àgbàlá rẹ̀.+   Ẹ tẹrí ba fún Jèhófà nínú ọ̀ṣọ́ mímọ́;+ Ẹ jẹ ìrora mímúná nítorí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ilẹ̀ ayé.+ 10  Ẹ wí láàárín àwọn orílẹ̀-èdè pé: “Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba.+ Ilẹ̀ eléso pẹ̀lú di èyí tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in tí a kò fi lè mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+ Òun yóò fi ìdúróṣánṣán gba ọ̀ràn ẹjọ́ àwọn ènìyàn rò.”+ 11  Kí ọ̀run kí ó yọ̀, kí ilẹ̀ ayé sì kún fún ìdùnnú.+ Kí òkun sán ààrá àti ohun tí ó kún inú rẹ̀.+ 12  Kí pápá gbalasa yọ ayọ̀ ńláǹlà àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀.+ Ní àkókò kan náà, kí gbogbo igi igbó fi ìdùnnu bú jáde+ 13  Níwájú Jèhófà. Nítorí ó ti wá;+ Nítorí ó ti wá ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé.+ Òun yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ eléso,+ Yóò sì fi ìṣòtítọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé