Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 95:1-11

95  Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a fi ìdùnnú ké jáde sí Jèhófà!+ Ẹ jẹ́ kí a kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun sí Àpáta ìgbàlà wa.+   Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ ti àwa ti ìdúpẹ́;+ Ẹ jẹ́ kí a fi àwọn orin atunilára kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun sí i.+   Nítorí pé Ọlọ́run ńlá ni Jèhófà+ Àti Ọba ńlá lórí gbogbo àwọn ọlọ́run yòókù,+   Ẹni tí àwọn ibi jíjinlẹ̀ jù lọ ní ilẹ̀ ayé wà lọ́wọ́ rẹ̀+ Àti ẹni tí àwọn téńté òkè ńláńlá jẹ́ tirẹ̀;+   Ẹni tí òkun, tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, jẹ́ tirẹ̀+ Àti ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ ṣẹ̀dá ilẹ̀ gbígbẹ.+   Ẹ wọlé wá, ẹ jẹ́ kí a jọ́sìn, kí a sì tẹrí ba;+ Ẹ jẹ́ kí a kúnlẹ̀+ níwájú Jèhófà Olùṣẹ̀dá wa.+   Nítorí òun ni Ọlọ́run wa, àwa sì ni àwọn ènìyàn pápá ìjẹko rẹ̀ àti àwọn àgùntàn ọwọ́ rẹ̀.+ Lónìí, bí ẹ bá fetí sí ohùn rẹ̀,+   Ẹ má ṣe sé ọkàn-àyà yín le bí ti Mẹ́ríbà,+ Bí ti ọjọ́ Másà ní aginjù,+   Nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò;+ Wọ́n wádìí mi wò, wọ́n sì rí ìgbòkègbodò mi.+ 10  Ogójì ọdún ni mo fi ń bá a nìṣó ní kíkórìíra ìran yẹn tẹ̀gbintẹ̀gbin,+ Mo sì tẹ̀ síwájú láti wí pé: “Wọ́n jẹ́ aṣèyówùú nínú ọkàn-àyà,+ Àwọn fúnra wọn kò sì wá mọ àwọn ọ̀nà mi”;+ 11  Ní ti àwọn tí mo búra nínú ìbínú mi pé:+ “Dájúdájú, wọn kì yóò wọ ibi ìsinmi mi.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé