Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 94:1-23

94  Jèhófà, Ọlọ́run tí ń gbẹ̀san,+ Ọlọ́run tí ń gbẹ̀san, tàn yanran!+   Gbé ara rẹ nà ró, ìwọ Onídàájọ́ ilẹ̀ ayé.+ Mú ẹ̀san iṣẹ́ padà wá sórí àwọn onírera.+   Jèhófà, yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ẹni burúkú,+ Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ẹni burúkú alára yóò máa yọ ayọ̀ ńláǹlà?+   Wọ́n ń sọ̀rọ̀ yàùyàù, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láìníjàánu;+ Gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ ń fọ́nnu nípa ara wọn.+   Jèhófà, wọ́n ń tẹ àwọn ènìyàn rẹ mọ́lẹ̀,+ Wọ́n sì ń ṣẹ́ ogún rẹ níṣẹ̀ẹ́.+   Wọ́n pa opó àti àtìpó,+ Wọ́n sì ṣìkà pa àwọn ọmọdékùnrin aláìníbaba.+   Wọ́n sì ń wí pé: “Jáà kò rí i;+ Ọlọ́run Jékọ́bù kò sì lóye rẹ̀.”+   Kí ẹ lóye, ẹ̀yin aláìnírònú nínú àwọn ènìyàn;+ Àti ní ti ẹ̀yin arìndìn, ìgbà wo ni ẹ óò ní ìjìnlẹ̀ òye èyíkéyìí?+   Ẹni tí ó gbin etí, ṣé kò lè gbọ́ ni?+ Tàbí kẹ̀, Ẹni tí ó ṣẹ̀dá ojú, ṣé kò lè rí ni?+ 10  Ẹni tí ń tọ́ àwọn orílẹ̀-èdè sọ́nà, ṣé kò lè fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà ni,+ Àní Ẹni tí ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ìmọ̀?+ 11  Jèhófà mọ ìrònú àwọn ènìyàn, pé bí èémí àmíjáde ni wọ́n jẹ́.+ 12  Aláyọ̀ ni abarapá ọkùnrin tí ìwọ tọ́ sọ́nà,+ Jáà, Àti ẹni tí ìwọ kọ́ láti inú òfin rẹ,+ 13  Láti fún un ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ kúrò nínú àwọn ọjọ́ ìyọnu àjálù,+ Títí a ó fi wa kòtò sílẹ̀ fún ẹni burúkú.+ 14  Nítorí pé Jèhófà kì yóò ṣá àwọn ènìyàn rẹ̀ tì,+ Bẹ́ẹ̀ ni kì yóò fi ogún tirẹ̀ sílẹ̀.+ 15  Nítorí pé ìpinnu ìdájọ́ yóò padà àní sí òdodo,+ Gbogbo àwọn adúróṣánṣán ní ọkàn-àyà yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 16  Ta ni yóò dìde fún mi ní ìdojú-ìjà-kọ àwọn aṣebi?+ Ta ni yóò mú ìdúró rẹ̀ fún mi ní ìdojú-ìjà-kọ àwọn aṣenilọ́ṣẹ́?+ 17  Bí kò ṣe pé Jèhófà ti jẹ́ ìrànwọ́ fún mi,+ Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ọkàn mi ì bá ti máa gbé inú ìdákẹ́jẹ́ẹ́.+ 18  Nígbà tí mo wí pé: “Ṣe ni ẹsẹ̀ mi yóò máa rìn tàgétàgé,”+ Jèhófà, inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ni ó ń gbé mi ró.+ 19  Nígbà tí ìrònú tí ń gbé mi lọ́kàn sókè di púpọ̀ nínú mi,+ Ìtùnú tìrẹ ni ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣìkẹ́ ọkàn mi.+ 20  Ìtẹ́ tí ń fa àgbákò yóò ha ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú rẹ+ Bí ó ti ń fi àṣẹ àgbékalẹ̀ dáná ìjàngbọ̀n?+ 21  Wọ́n ń gbéjà ko ọkàn olódodo lọ́nà mímúná,+ Wọ́n sì ń pe ẹ̀jẹ̀ aláìmọwọ́-mẹsẹ̀ pàápàá ní ohun burúkú.+ 22  Ṣùgbọ́n Jèhófà yóò di ibi gíga ààbò fún mi,+ Ọlọ́run mi yóò sì di àpáta ìsádi mi.+ 23  Òun yóò sì yí ọṣẹ́ wọn dà sí wọn lórí,+ Yóò sì fi ìyọnu àjálù tiwọn pa wọ́n lẹ́nu mọ́.+ Jèhófà Ọlọ́run wa yóò pa wọ́n lẹ́nu mọ́.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé