Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 93:1-5

93  Jèhófà fúnra rẹ̀ ti di ọba!+ Ó gbé ọlá ògo wọ̀;+ Jèhófà gbé e wọ̀—ó ti fi okun di ara rẹ̀ lámùrè.+ Ilẹ̀ eléso pẹ̀lú di èyí tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in tí a kò fi lè mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+   Ìtẹ́ rẹ fìdí múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn;+ Ìwọ wà láti àkókò tí ó lọ kánrin.+   Àwọn odò gbé e sókè, Jèhófà, Àwọn odò gbé ìró wọn sókè;+ Àwọn odò ń gbé ìró ìbìlù wọn sókè ṣáá.+   Lékè àwọn ìró alagbalúgbú omi, ọlọ́lá ńlá ìgbì òkun tí ń fọ́n ká di ìfóófòó,+ Ọlọ́lá ńlá+ ni Jèhófà ní ibi gíga.   Àwọn ìránnilétí rẹ ti já sí aṣeégbẹ́kẹ̀lé+ gan-an. Ìjẹ́mímọ́ yẹ ilé rẹ,+ Jèhófà, fún ọjọ́ gígùn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé