Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 92:1-15

Orin atunilára, orin, fún ọjọ́ sábáàtì. 92  Ó dára láti máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà+ Àti láti máa kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ, ìwọ Ẹni Gíga Jù Lọ;+   Láti máa sọ̀rọ̀ nípa inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́+ ní òwúrọ̀ Àti nípa ìṣòtítọ́ rẹ ní òròòru,+   Lórí ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín mẹ́wàá àti lórí gòjé,+ Nípasẹ̀ ohùn orin adún-lọ-rére lórí háàpù.+   Nítorí pé ìwọ, Jèhófà, ti mú kí n máa yọ̀ nítorí ìgbòkègbodò rẹ; Mo ń fi ìdùnnú ké jáde nítorí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.+   Àwọn iṣẹ́ rẹ mà tóbi o, Jèhófà!+ Ìrònú rẹ jinlẹ̀ gidigidi.+   Kò sí aláìnírònú tí ó lè mọ̀ wọ́n,+ Kò sì sí arìndìn tí ó lè lóye èyí.+   Nígbà tí àwọn ẹni burúkú bá rú jáde bí ewéko,+ Tí gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ bá sì yọ ìtànná, Kí a lè pa wọ́n rẹ́ ráúráú títí láé ni.+   Ṣùgbọ́n ìwọ, Jèhófà, ń bẹ ní ibi gíga lókè fún àkókò tí ó lọ kánrin.+   Nítorí, wò ó! àwọn ọ̀tá rẹ, Jèhófà,+ Nítorí, wò ó! àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé;+ Gbogbo àwọn aṣenilọ́ṣẹ́ ni a óò pín níyà sí ara wọn.+ 10  Ṣùgbọ́n ìwọ yóò gbé ìwo mi ga bí ti akọ màlúù ìgbẹ́;+ Èmi yóò fi ọ̀tun òróró kunra.+ 11  Ojú mi yóò sì máa wo àwọn ọ̀tá mi;+ Etí mi yóò gbọ́ nípa àwọn ènìyàn náà gan-an tí ó dìde sí mi, àní àwọn aṣebi. 12  Olódodo yóò yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí igi ọ̀pẹ;+ Gẹ́gẹ́ bí kédárì ní Lẹ́bánónì, òun yóò di ńlá.+ 13  Àwọn tí a gbìn sí ilé Jèhófà,+ Nínú àwọn àgbàlá Ọlọ́run wa,+ wọn yóò yọ ìtànná. 14  Wọn yóò ṣì máa gbèrú nígbà orí ewú,+ Wọn yóò máa bá a lọ ní sísanra àti ní jíjàyọ̀yọ̀,+ 15  Láti lè sọ pé adúróṣánṣán ni Jèhófà.+ Òun ni Àpáta mi,+ ẹni tí kò sí àìṣòdodo kankan nínú rẹ̀.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé