Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 90:1-17

Àdúrà Mósè, ènìyàn Ọlọ́run tòótọ́.+ 90  Jèhófà, ìwọ tìkára rẹ ti jẹ́ ibùgbé gidi fún wa+ Ní ìran dé ìran.+   Àní kí a tó bí àwọn òkè ńlá,+ Tàbí kí o tó bẹ̀rẹ̀ sí bí ilẹ̀ ayé+ àti ilẹ̀ eléso+ gẹ́gẹ́ bí ẹni pé pẹ̀lú ìrora ìrọbí, Àní láti àkókò tí ó lọ kánrin títí dé àkókò tí ó lọ kánrin, ìwọ ni Ọlọ́run.+   Ìwọ mú kí ẹni kíkú padà di ohun àtẹ̀rẹ́,+ Ìwọ sì wí pé: “Ẹ padà lọ, ẹ̀yin ọmọ ènìyàn.”+   Nítorí pé lójú rẹ, ẹgbẹ̀rún ọdún dà bí kìkì àná nígbà tí ó bá kọjá,+ Àti bí ìṣọ́ kan ní òru.+   Ìwọ ti gbá wọn lọ;+ wọ́n di oorun lásán-làsàn;+ Ní òwúrọ̀, wọ́n dà bí koríko tútù tí ń yí padà.+   Ní òwúrọ̀, ó mú ìtànná jáde, yóò sì yí padà;+ Ní ìrọ̀lẹ́, ó rọ, ó sì gbẹ dànù dájudájú.+   Nítorí pé a ti wá sí òpin nínú ìbínú rẹ,+ Ìhónú rẹ sì ti yọ wá lẹ́nu.+   Ìwọ ti gbé ìṣìnà wa kalẹ̀ sí ọ̀gangan iwájú rẹ,+ Àwọn nǹkan àṣírí wa sí iwájú rẹ tí ó mọ́lẹ̀ yòò.+   Nítorí pé gbogbo ọjọ́ wa ti ń lọ sí òpin wọn nínú ìbínú kíkan rẹ;+ Àwa ti parí àwọn ọdún wa gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ wúyẹ́wúyẹ́.+ 10  Nínú ara wọn, ọjọ́ àwọn ọdún wa jẹ́ àádọ́rin ọdún;+ Bí wọ́n bá sì jẹ́ ọgọ́rin ọdún nítorí àkànṣe agbára ńlá,+ Síbẹ̀, wíwà nìṣó wọn jẹ́ lórí ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́;+ Nítorí pé kíákíá ni yóò kọjá lọ, àwa yóò sì fò lọ.+ 11  Ta ní ń bẹ tí ó mọ okun ìbínú rẹ+ Àti ìbínú kíkan rẹ ní ìbámu pẹ̀lú ìbẹ̀rù rẹ?+ 12  Fi hàn wá, àní bí àwa yóò ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa+ Ní irú ọ̀nà tí a ó fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.+ 13  Padà, Jèhófà!+ Yóò ti pẹ́ tó?+ Kí o sì kẹ́dùn nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ.+ 14  Fi inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀,+ Kí a lè fi ìdùnnú ké jáde, kí a sì lè máa yọ̀ ní gbogbo ọjọ́ wa.+ 15  Mú kí a máa yọ̀ lọ́nà tí ó ṣe rẹ́gí pẹ̀lú àwọn ọjọ́ tí ìwọ fi ṣẹ́ wa níṣẹ̀ẹ́,+ Àwọn ọdún tí a fi rí ìyọnu àjálù.+ 16  Kí ìgbòkègbodò rẹ hàn sí àwọn ìránṣẹ́ tìrẹ,+ Kí ọlá ńlá rẹ sì hàn lára àwọn ọmọ wọn.+ 17  Kí adùn Jèhófà Ọlọ́run wa sì wà lára wa,+ Kí o sì fìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in lára wa.+ Bẹ́ẹ̀ ni, iṣẹ́ ọwọ́ wa, kí o fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé