Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 9:1-20

Sí olùdarí lórí Muti-lábénì. Orin atunilára ti Dáfídì. א [Áléfì] 9  Ṣe ni èmi yóò máa fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbé ọ lárugẹ, Jèhófà;+Èmi yóò máa polongo gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+   Ṣe ni èmi yóò máa yọ̀, èmi yóò sì máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nínú rẹ,+Èmi yóò máa kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ, ìwọ Ẹni Gíga Jù Lọ.+ ב [Bétì]   Nígbà tí àwọn ọ̀tá mi bá yí padà,+Wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣègbé kúrò níwájú rẹ.+   Nítorí pé o ti mú ìdájọ́ mi àti ẹjọ́ mi ṣẹ ní kíkún;+O ti jókòó sórí ìtẹ́ ní fífi òdodo ṣe ìdájọ́.+ ג [Gímélì]   O ti bá àwọn orílẹ̀-èdè wí lọ́nà mímúná,+ o ti pa ẹni burúkú run.+Orúkọ wọn ni o ti nù kúrò fún àkókò tí ó lọ kánrin, àní títí láé.+   Ìwọ ọ̀tá, ìsọdahoro rẹ ni a ti ṣe ni àṣepé títí lọ fáàbàdà,+Àti àwọn ìlú ńlá tí o ti fà tu.+Àní mímẹ́nukàn wọ́n yóò ṣègbé dájúdájú.+ ה [Híì]   Ní ti Jèhófà, yóò jókòó fún àkókò tí ó lọ kánrin,+Ní fífìdí ìtẹ́ rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in fún ìdájọ́ pàápàá.+   Òun fúnra rẹ̀ yóò sì ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ eléso ní òdodo;+Yóò ṣe ìgbẹ́jọ́ àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè ní ìdúróṣánṣán.+ ו [Wọ́ọ̀]   Jèhófà yóò sì di ibi gíga ààbò fún ẹni tí a ni lára,+Ibi gíga ààbò ní àwọn àkókò wàhálà.+ 10  Àwọn tí ó mọ orúkọ rẹ yóò sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ,+Nítorí tí ìwọ, Jèhófà, kì yóò fi àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀ dájúdájú.+ ז [Sáyínì] 11  Ẹ kọ orin atunilára sí Jèhófà, ẹni tí ń gbé Síónì;+Ẹ sọ àwọn ìṣe rẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn.+ 12  Nítorí pé, nígbà tí ó bá ń wá ìtàjẹ̀sílẹ̀,+ dájúdájú, òun yóò rántí àwọn wọ̀nyẹn gan-an;+Ó dájú pé kò ní gbàgbé igbe ẹkún àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.+ ח [Kétì] 13  Fi ojú rere hàn sí mi, Jèhófà; rí ìṣẹ́ tí àwọn tí ó kórìíra mi fi ń ṣẹ́ mi,+Ìwọ tí ń gbé mi sókè láti àwọn ẹnubodè ikú,+ 14  Kí n lè polongo gbogbo àwọn iṣẹ́ rẹ tí ó yẹ fún ìyìn+Ní àwọn ẹnubodè+ ọmọbìnrin Síónì,+Kí n lè kún fún ìdùnnú nínú ìgbàlà rẹ.+ ט [Tétì] 15  Àwọn orílẹ̀-èdè ti rì sínú kòtò tí wọ́n gbẹ́;+Inú àwọ̀n+ tí wọ́n fi pa mọ́, ni a ti gbá ẹsẹ̀ àwọn fúnra wọn mú.+ 16  Jèhófà ni a mọ̀ nípasẹ̀ ìdájọ́ tí ó ti mú ṣẹ ní kíkún.+Nípasẹ̀ ìgbòkègbodò ọwọ́ ara rẹ̀ ni a fi dẹkùn mú ẹni burúkú.+Hígáíónì. Sélà. י [Yódì] 17  Àwọn ènìyàn burúkú+ yóò padà sí Ṣìọ́ọ̀lù,+Àní gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ó bá gbàgbé Ọlọ́run.+ 18  Nítorí pé a kì yóò fi ìgbà gbogbo gbàgbé àwọn òtòṣì,+Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí àwọn ọlọ́kàn tútù kì yóò ṣègbé láé.+ כ [Káfì] 19  Dìde, Jèhófà! Má ṣe jẹ́ kí ẹni kíkú fi àjùlọ hàn nínú okun.+Jẹ́ kí a ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè níwájú rẹ.+ 20  Dẹ́rù bà wọ́n, Jèhófà,+Kí àwọn orílẹ̀-èdè lè mọ̀ pé ẹni kíkú lásán ni wọ́n.+ Sélà.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé