Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 89:1-52

Másíkílì. Ti Étánì tí í ṣe Ẹ́síráhì.+ 89  Àwọn ìfihàn inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ti Jèhófà ni èmi yóò máa fi ṣe orin kọ àní fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Ní ìran dé ìran ni èmi yóò máa fi ẹnu mi sọ ìṣòtítọ́ rẹ di mímọ̀.+   Nítorí èmi ti wí pé: “A óò gbé inú-rere-onífẹ̀ẹ́ ró àní fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ Ní ti ọ̀run, ìwọ fìdí ìṣòtítọ́ rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in nínú rẹ̀.”+   “Èmi ti bá àyànfẹ́ mi dá májẹ̀mú;+ Èmi ti búra fún Dáfídì ìránṣẹ́ mi+ pé,   ‘Àní fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò fìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in,+ Ṣe ni èmi yóò sì gbé ìtẹ́ rẹ ró+ ní ìran dé ìran.’” Sélà.   Ọ̀run yóò sì gbé ohun ìyanu tí ìwọ ṣe lárugẹ, Jèhófà,+ Bẹ́ẹ̀ ni, ìṣòtítọ́ rẹ nínú ìjọ àwọn ẹni mímọ́.   Nítorí pé ta ni ó wà ní sánmà tí a lè fi wé Jèhófà?+ Ta ni ó lè jọ Jèhófà lára àwọn ọmọ Ọlọ́run?+   Ọlọ́run ni kí a ní ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ fún ní àwùjọ tímọ́tímọ́ ti àwọn ẹni mímọ́;+ Ó jẹ́ atóbilọ́lá àti amúnikún-fún-ẹ̀rù lórí gbogbo àwọn tí ó yí i ká.+   Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun,+ Ta ni ó ní okun inú bí ìwọ, Jáà?+ Ìṣòtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.+   Ìwọ ń ṣàkóso lórí ìrusókè òkun;+ Nígbà tí ó bá gbé ìgbì rẹ̀ dìde, ìwọ tìkára rẹ ni ó ń mú un pa rọ́rọ́.+ 10  Ìwọ tìkára rẹ ti tẹ Ráhábù rẹ́,+ àní gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a pa.+ Ìwọ ti fi apá okun rẹ tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.+ 11  Tìrẹ ni ọ̀run,+ tìrẹ sì ni ilẹ̀ ayé pẹ̀lú;+ Ilẹ̀ eléso àti ohun tí ó kún inú rẹ̀+—ìwọ tìkára rẹ ni ó fi ìpìlẹ̀ wọn sọlẹ̀.+ 12  Àríwá àti gúúsù—ìwọ tìkára rẹ ni ó dá wọn;+ Tábórì+ àti Hámónì+—wọ́n ń fi ìdùnnú ké jáde ní orúkọ rẹ.+ 13  Apá tí ó ní agbára ńlá jẹ́ tìrẹ,+ Ọwọ́ rẹ le,+ Ọwọ́ ọ̀tún rẹ ni a gbé ga.+ 14  Òdodo àti ìdájọ́ ni ibi àfìdímúlẹ̀ ìtẹ́ rẹ;+ Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ wá sí iwájú rẹ.+ 15  Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí ó mọ igbe ìdùnnú.+ Jèhófà, inú ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ ni wọ́n ti ń rìn.+ 16  Wọ́n ń kún fún ìdùnnú láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ ní orúkọ rẹ,+ A sì gbé wọn ga nínú òdodo rẹ.+ 17  Nítorí pé ìwọ ni ẹwà okun wọn;+ Nípa ìfẹ́ rere rẹ ni a sì fi gbé ìwo wa ga.+ 18  Nítorí pé ti Jèhófà ni apata wa,+ Ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì sì ni ọba wa.+ 19  Ní àkókò yẹn, ìwọ bá àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ sọ̀rọ̀ nínú ìran,+ Ìwọ sì tẹ̀ síwájú láti sọ pé: “Èmi ti pèsè ìrànlọ́wọ́ fún alágbára ńlá;+ Èmi ti gbé àyànfẹ́ kan ga nínú àwọn ènìyàn.+ 20  Èmi ti rí Dáfídì ìránṣẹ́ mi;+ Èmi ti fi òróró mímọ́ mi yàn án,+ 21  Ẹni tí ọwọ́ mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in,+ Ẹni tí apá tèmi yóò fún lókun pẹ̀lú.+ 22  Ọ̀tá kankan kì yóò fi tipátipá gba nǹkan lọ́wọ́ rẹ̀,+ Bẹ́ẹ̀ ni ọmọ àìṣòdodo èyíkéyìí kì yóò ṣẹ́ ẹ níṣẹ̀ẹ́.+ 23  Èmi sì fọ́ àwọn elénìní rẹ̀ sí wẹ́wẹ́ kúrò níwájú rẹ̀,+ Mo sì ń mú ìyọnu àgbálù bá àwọn tí ó kórìíra rẹ̀ lọ́nà gbígbóná janjan.+ 24  Ìṣòtítọ́ mi àti inú rere mi onífẹ̀ẹ́ sì wà pẹ̀lú rẹ̀,+ Orúkọ mi ni a sì fi gbé ìwo rẹ̀ ga.+ 25  Èmi sì ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lé òkun+ Àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ lé àwọn odò.+ 26  Òun fúnra rẹ̀ ké pè mí pé, ‘Ìwọ ni Baba mi,+ Ọlọ́run mi+ àti Àpáta ìgbàlà mi.’+ 27  Pẹ̀lúpẹ̀lù, èmi alára yóò fi í ṣe àkọ́bí,+ Ẹni gíga jù lọ nínú àwọn ọba ilẹ̀ ayé.+ 28  Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni èmi yóò pa inú rere mi onífẹ̀ẹ́ mọ́ sí i,+ Májẹ̀mú mi yóò sì jẹ́ aṣeégbíyèlé sí i.+ 29  Dájúdájú, èmi yóò sì gbé irú-ọmọ rẹ̀ kalẹ̀ títí láé+ Àti ìtẹ́ rẹ̀ bí àwọn ọjọ́ ọ̀run.+ 30  Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá fi òfin mi sílẹ̀,+ Tí wọn kò sì rìn nínú àwọn ìpinnu ìdájọ́ mi,+ 31  Bí wọ́n bá sọ àwọn ìlànà àgbékalẹ̀ tèmi di aláìmọ́, Tí wọn kò sì pa àwọn àṣẹ tèmi mọ́, 32  Èmi yóò sì fi ọ̀pá yí àfiyèsí mi sí ìrélànàkọjá wọn,+ Àní èmi yóò fi ẹgba yí àfiyèsí mi sí ìṣìnà wọn.+ 33  Ṣùgbọ́n inú rere mi onífẹ̀ẹ́ ni èmi kì yóò mú kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀,+ Bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò já sí èké ní ti ìṣòtítọ́ mi.+ 34  Èmi kì yóò sọ májẹ̀mú mi di aláìmọ́,+ Èmi kì yóò sì yí gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí ó ti ètè mi jáde padà.+ 35  Ẹ̀ẹ̀kan ni mo ti fi ìjẹ́mímọ́ mi búra,+ Èmi kì yóò purọ́ fún Dáfídì.+ 36  Irú-ọmọ rẹ̀ yóò wà àní fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ Àti ìtẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí oòrùn ní iwájú mi.+ 37  A ó fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in gẹ́gẹ́ bí òṣùpá fún àkókò tí ó lọ kánrin, Àti gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé ní sánmà.” Sélà. 38  Ṣùgbọ́n ìwọ—ìwọ ti ta nù, ìwọ sì ń fojú pa rẹ́;+ Ìwọ ti bínú kíkankíkan sí ẹni àmì òróró rẹ.+ 39  Ìwọ ti kọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ rẹ sílẹ̀ tẹ̀gàntẹ̀gàn; Ìwọ ti sọ adé dáyádémà rẹ̀ di aláìmọ́ títí dé ilẹ̀yílẹ̀.+ 40  Ìwọ ti wó gbogbo ọgbà ẹran rẹ̀ tí a fi òkúta ṣe lulẹ̀+; Ìwọ ti mú ìparun bá àwọn odi rẹ̀.+ 41  Gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ lójú ọ̀nà ti kó o ní ìkógun;+ Ó ti di ẹ̀gàn sí àwọn aládùúgbò rẹ̀.+ 42  Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún àwọn elénìní rẹ̀ ga;+ Ìwọ ti mú kí gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ̀ máa yọ̀.+ 43  Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwọ tún hùwà sí idà rẹ̀ bí ọ̀tá,+ Ìwọ sì ti mú kí ó má ṣe ní ìtẹ̀síwájú nínú ìjà ogun.+ 44  Ìwọ ti mú kí ó pàdánù ìdángbinrin rẹ̀,+ Ìtẹ́ rẹ̀ ni ìwọ sì ti fi sọ̀kò sí ilẹ̀yílẹ̀.+ 45  Ìwọ ti ké àwọn ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀ kúrú; Ìwọ ti fi ìtìjú bò ó.+ Sélà. 46  Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí ìwọ yóò máa bá a nìṣó ní fífi ara rẹ pa mọ́? Ṣé títí lọ ni?+ Ìhónú rẹ yóò ha máa bá a nìṣó ní jíjó bí iná?+ 47  Rántí ibi tí ọjọ́ ayé mi mọ.+ Lásán ha ni ìwọ dá gbogbo ọmọ ènìyàn bí?+ 48  Abarapá ọkùnrin wo ni ó wà láàyè tí kì yóò rí ikú?+ Ó ha lè pèsè àsálà fún ọkàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ Ṣìọ́ọ̀lù bí?+ Sélà. 49  Àwọn ìṣe inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ti àtijọ́ dà, Jèhófà, Èyí tí o búra nípa rẹ̀ fún Dáfídì nínú ìṣòtítọ́ rẹ?+ 50  Jèhófà, rántí ẹ̀gàn tí ń bẹ lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ,+ Rírù tí mo ń ru ẹ̀gàn gbogbo àwọn ènìyàn púpọ̀ ní oókan àyà mi,+ 51  Bí àwọn ọ̀tá rẹ ti pẹ̀gàn, Jèhófà,+ Bí wọ́n ti pẹ̀gàn àwọn ojú ẹsẹ̀ ẹni àmì òróró rẹ.+ 52  Ìbùkún ni fún Jèhófà fún àkókò tí ó lọ kánrin. Àmín àti Àmín.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé