Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 88:1-18

Orin, orin atunilára ti àwọn ọmọ Kórà. Sí olùdarí lórí Máhálátì fún dídáhùn padà. Másíkílì ti Hémánì+ tí í ṣe Ẹ́síráhì. 88  Ìwọ Jèhófà, Ọlọ́run ìgbàlà mi,+ Mo ti ké jáde ní ọ̀sán,+ Àti ní òru pẹ̀lú ní iwájú rẹ.+   Iwájú rẹ ni àdúrà mi yóò wá.+ Dẹ etí sí igbe ìpàrọwà mi.+   Nítorí pé ọkàn mi ti ní ànító ìyọnu àjálù,+ Àní ìwàláàyè mi ti sún mọ́ Ṣìọ́ọ̀lù pẹ́kípẹ́kí.+   A ti kà mí mọ́ ara àwọn tí ń sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú kòtò;+ Mo ti dà bí abarapá ọkùnrin tí kò ní okun,+   Tí a dá sílẹ̀ láàárín àwọn òkú,+ Bí àwọn tí a pa tí wọ́n dùbúlẹ̀ ní ibi ìsìnkú,+ Àwọn tí ìwọ kò tún rántí mọ́, Tí a sì ti yà nípa sí ọwọ́ rẹ tí ń ranni lọ́wọ́.+   Ìwọ ti fi mí sínú kòtò tí ó jìn sísàlẹ̀ jù lọ, Nínú àwọn ibi tí ó ṣókùnkùn, nínú ọ̀gbun ńlá àìnísàlẹ̀.+   Ìhónú rẹ ti sọ ara rẹ̀ lù mí,+ Ìwọ sì ti fi gbogbo ìgbì rẹ tí ń fọ́n ká di ìfóófòó ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́.+ Sélà.   Ìwọ ti mú àwọn ojúlùmọ̀ mi jìnnà réré sí mi;+ Ìwọ ti gbé mi kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìṣe-họ́ọ̀-sí gidigidi sí wọn.+ Mo wà lábẹ́ ìkálọ́wọ́kò, n kò sì lè jáde.+   Ojú mi ti láálàṣí nítorí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́.+ Mo ti ké pè ọ́, Jèhófà, láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀;+ Ìwọ ni mo tẹ́ àtẹ́lẹwọ́ mi sí.+ 10  Ìwọ yóò ha ṣe ohun ìyanu fún àwọn tí ó ti kú bí?+ Tàbí kẹ̀, àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú yóò ha dìde,+ Wọn yóò ha gbé ọ lárugẹ bí?+ Sélà. 11  A ó ha polongo inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ní ibi ìsìnkú bí, Ìṣòtítọ́ rẹ ní ibi ìparun bí?+ 12  A ó ha mọ ohun ìyanu tí o ṣe nínú òkùnkùn bí,+ Tàbí òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé bí?+ 13  Síbẹ̀síbẹ̀, ìwọ, Jèhófà, ni èmi tìkára mi ti kígbe pè fún ìrànlọ́wọ́,+ Àti ní òwúrọ̀, àdúrà mi ń kò ọ́ lójú ṣáá.+ 14  Jèhófà, èé ṣe tí ìwọ fi ta ọkàn mi nù?+ Èé ṣe tí ìwọ fi ojú rẹ pa mọ́ fún mi?+ 15  A ń ṣẹ́ mi níṣẹ̀ẹ́, mo sì fẹ́rẹ̀ẹ́ gbẹ́mìí mì láti ìgbà ọmọdékùnrin mi wá;+ Mo ti gba àwọn ohun tí ń da jìnnìjìnnì boni láti ọ̀dọ̀ rẹ sára gan-an.+ 16  Ìkọmànà rẹ ti ìbínú jíjófòfò ti kọjá lára mi;+ Ìpayà láti ọ̀dọ̀ ìwọ tìkára rẹ ti pa mí lẹ́nu mọ́.+ 17  Wọ́n ti yí mi ká bí omi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀;+ Wọ́n ti ká mi mọ́ lẹ́ẹ̀kan náà. 18  Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti alábàákẹ́gbẹ́ jìnnà réré sí mi;+ Ibi tí ó ṣókùnkùn ni àwọn ojúlùmọ̀ mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé