Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 87:1-7

Ti àwọn ọmọ Kórà. Orin atunilára, orin. 87  Ìpìlẹ̀ rẹ̀ ń bẹ ní àwọn òkè ńlá mímọ́.+   Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹnubodè Síónì gidigidi+ Ju gbogbo àgọ́ Jékọ́bù.+   Àwọn ohun ológo ni a ń sọ nípa rẹ, ìwọ ìlú ńlá Ọlọ́run tòótọ́.+ Sélà.   Èmi yóò mẹ́nu kan Ráhábù+ àti Bábílónì+ pé wọ́n wà lára àwọn tí ó mọ̀ mí; Filísíà+ àti Tírè nìyí, pa pọ̀ pẹ̀lú Kúṣì: “Ẹni yìí ni a bí níbẹ̀.”+   Àti ní ti Síónì, a óò wí pé: “Gbogbo wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ni a bí nínú rẹ̀.”+ Ẹni Gíga Jù Lọ+ tìkára rẹ̀ yóò sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in.+   Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò polongo, nígbà ṣíṣe àkọsílẹ̀ àwọn ènìyàn+ pé: “Ẹni yìí ni a bí níbẹ̀.”+ Sélà.   Àwọn akọrin àti àwọn tí ń jó ijó àjóyípo yóò wà:+ “Gbogbo ìsun mi ń bẹ nínú rẹ.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé