Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 86:1-17

Àdúrà Dáfídì. 86  Dẹ etí sílẹ̀, Jèhófà. Dá mi lóhùn,+Nítorí pé ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ àti òtòṣì ni mí.+   Ṣọ́ ọkàn mi, nítorí pé adúróṣinṣin ni mí.+Gba ìránṣẹ́ rẹ là—ìwọ ni Ọlọ́run mi—tí ó gbẹ́kẹ̀ lé ọ.+   Fi ojú rere hàn sí mi, Jèhófà,+Nítorí pé ìwọ ni mo ń ké pè láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+   Mú kí ọkàn ìránṣẹ́ rẹ máa yọ̀,+Nítorí pé ìwọ, Jèhófà, ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.+   Nítorí pé ẹni rere+ ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini;+Inú-rere-onífẹ̀ẹ́ sí gbogbo àwọn tí ń ké pè ọ́ sì pọ̀ yanturu.+   Fi etí sí àdúrà mi, Jèhófà;+Sì fiyè sí ohùn ìpàrọwà mi.+   Ṣe ni èmi yóò ké pè ọ́ ní ọjọ́ wàhálà mi,+Nítorí pé ìwọ yóò dá mi lóhùn.+   Jèhófà, kò sí ẹni tí ó dà bí rẹ nínú àwọn ọlọ́run,+Bẹ́ẹ̀ ni kò sí iṣẹ́ kankan tí ó dà bí tìrẹ.+   Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ ṣe yóò tìkára wọn wá,+Wọn yóò sì tẹrí ba níwájú rẹ, Jèhófà,+Wọn yóò sì fi ògo fún orúkọ rẹ.+ 10  Nítorí pé ẹni ńlá ni ọ́, o sì ń ṣe àwọn ohun àgbàyanu;+Ìwọ ni Ọlọ́run, ìwọ nìkan ṣoṣo.+ 11  Jèhófà, fún mi ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà rẹ.+Èmi yóò máa rìn nínú òtítọ́ rẹ.+Mú ọkàn-àyà mi ṣọ̀kan láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ.+ 12  Èmi yóò fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbé ọ lárugẹ,+ ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi,Ṣe ni èmi yóò sì máa yin orúkọ rẹ lógo fún àkókò tí ó lọ kánrin, 13  Nítorí pé títóbi ni inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ sí mi,+Ìwọ sì ti dá ọkàn mi nídè kúrò nínú Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ó rẹlẹ̀ jù lọ nínú rẹ̀.+ 14  Ọlọ́run, àní àwọn oníkùgbù ti dìde sí mi;+Àní àpéjọ àwọn afìkà-gboni-mọ́lẹ̀ ti wá ọkàn mi,+Wọn kò sì gbé ọ sí iwájú ara wọn.+ 15  Ṣùgbọ́n ìwọ, Jèhófà, jẹ́ Ọlọ́run aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́,+Tí ń lọ́ra láti bínú,+ tí ó sì pọ̀ yanturu nínú inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́.+ 16  Yíjú sí mi, kí o sì fi ojú rere hàn sí mi.+Fi okun rẹ fún ìránṣẹ́ rẹ,+Kí o sì gba ọmọ ẹrúbìnrin rẹ là.+ 17  Ṣiṣẹ́ àmì tí ó túmọ̀ sí oore fún mi,Kí àwọn tí ó kórìíra mi lè rí i, kí ojú sì tì wọ́n.+Nítorí pé ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, ti ràn mí lọ́wọ́, o sì ti tù mí nínú.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé