Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 85:1-13

Fún olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà. Orin atunilára. 85  Jèhófà, ìwọ ti ní ìdùnnú sí ilẹ̀ rẹ;+Ìwọ ti mú àwọn tí a mú ní òǹdè lára Jékọ́bù padà wá.+   Ìwọ ti dárí ìṣìnà àwọn ènìyàn rẹ jì;+Ìwọ ti bo gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+ Sélà.   Ìwọ ti ṣàkóso gbogbo ìbínú kíkan rẹ;+Ìwọ ti yí padà kúrò nínú ooru ìbínú rẹ.+   Kó wa jọ padà, ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà wa,+Kí o sì mú ìbínú rẹ sí wa kúrò.+   Ṣé fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ìbínú rẹ yóò fi ru sókè sí wa ni?+Ìwọ yóò ha fa ìbínú rẹ gùn láti ìran dé ìran bí?+   Ìwọ tìkára rẹ kì yóò ha tún sọ wá di ààyè bí,+Kí àwọn ènìyàn rẹ lè máa yọ̀ nínú rẹ?+   Jèhófà, fi inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ hàn sí wa,+Ìgbàlà rẹ sì ni kí o fi fún wa.+   Dájúdájú, èmi yóò gbọ́ ohun tí Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́ yóò sọ,+Nítorí tí yóò sọ̀rọ̀ àlàáfíà fún àwọn ènìyàn rẹ̀+ àti fún àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀,Ṣùgbọ́n kí wọ́n má padà sí gbígbọ́kàn lé ara wọn.+   Dájúdájú, ìgbàlà rẹ̀ sún mọ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀,+Kí ògo lè máa gbé ní ilẹ̀ wa.+ 10  Ní ti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́, wọ́n ti bá ara wọn pàdé;+Òdodo àti àlàáfíà—wọ́n ti fi ẹnu ko ara wọn lẹ́nu.+ 11  Àní òótọ́ yóò rú jáde láti inú ilẹ̀,+Òdodo yóò sì bojú wolẹ̀ àní láti ọ̀run.+ 12  Pẹ̀lúpẹ̀lù, Jèhófà, ní tirẹ̀, yóò fúnni ní ohun tí ó dára,+Ilẹ̀ wa yóò sì máa mú èso rẹ̀ wá.+ 13  Àní òdodo yóò máa rìn níwájú rẹ̀,+Yóò sì fi àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ la ọ̀nà.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé