Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 84:1-12

Fún olùdarí lórí Gítítì.+ Ti àwọn ọmọ Kórà. Orin atunilára. 84  Àgọ́ ìjọsìn rẹ títóbi lọ́lá mà dára lẹ́wà o,+Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun!+   Ọkàn mi ti ṣàfẹ́rí, ó sì ti joro lẹ́nu wíwọ̀nà fún àwọn àgbàlá Jèhófà.+Ọkàn-àyà mi àti ẹran ara mi fi ìdùnnú ké jáde sí Ọlọ́run alààyè.+   Àní ẹyẹ ti rí ilé,Alápàáǹdẹ̀dẹ̀ sì ti rí ìtẹ́ fún ara rẹ̀,Ibi tí ó fi àwọn ọmọ rẹ̀ sí—Pẹpẹ rẹ títóbi lọ́lá, Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, Ọba mi àti Ọlọ́run mi!   Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbé inú ilé rẹ!+Wọ́n ṣì ń bá a nìṣó ní yíyìn ọ́.+ Sélà.   Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí okun wọn ń bẹ nínú rẹ,+Àwọn tí òpópó ń bẹ nínú ọkàn-àyà wọn.+   Ní gbígba pẹ̀tẹ́lẹ̀ rírẹlẹ̀ àwọn igi bákà+ kọjá lọ,Wọ́n sọ ọ́ di ìsun;Àní ìbùkún ni olùkọ́ni+ fi bo ara rẹ̀.   Wọn yóò máa rìn lọ láti ìmí dé ìmí;+Olúkúlùkù fara han Ọlọ́run ní Síónì.+   Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, gbọ́ àdúrà mi;+Fi etí sílẹ̀, ìwọ Ọlọ́run Jékọ́bù.+ Sélà.   Ìwọ apata wa, wò ó, Ọlọ́run,+Kí o sì wo ojú ẹni àmì òróró rẹ.+ 10  Nítorí pé ọjọ́ kan nínú àwọn àgbàlá rẹ sàn ju ẹgbẹ̀rún ọjọ́ níbòmíràn.+Mo ti yàn láti máa dúró ní ibi àbáwọ ilé Ọlọ́run mi+Kàkà kí n máa rìn kiri nínú àwọn àgọ́ ìwà burúkú.+ 11  Nítorí pé Jèhófà Ọlọ́run jẹ́ oòrùn+ àti apata;+Ojú rere àti ògo ni ó ń fi fúnni.+Jèhófà tìkára rẹ̀ kì yóò fawọ́ ohunkóhun tí ó dára sẹ́yìn lọ́dọ̀ àwọn tí ń rìn ní àìlálèébù.+ 12  Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, aláyọ̀ ni ènìyàn tí ó gbẹ́kẹ̀ lé ọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé