Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 83:1-18

Orin. Orin atunilára ti Ásáfù.+ 83  Ọlọ́run, má ṣe jẹ́ kí ìdákẹ́jẹ́ẹ́ wà níhà ọ̀dọ̀ rẹ;+ Má ṣe máa bá a nìṣó ní ṣíṣàìsọ̀rọ̀, má sì dúró jẹ́ẹ́, Olú Ọ̀run.+   Nítorí, wò ó! àní àwọn ọ̀tá rẹ wà nínú ìrọ́kẹ̀kẹ̀;+ Àní àwọn tí ó kórìíra rẹ lọ́nà gbígbóná janjan ti gbé orí wọn sókè.+   Wọ́n ń bá ọ̀rọ̀ àṣírí wọn lọ lọ́nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí lòdì sí àwọn ènìyàn rẹ;+ Wọ́n sì di tẹ̀ǹbẹ̀lẹ̀kun sí àwọn tí ìwọ fi pa mọ́.+   Wọ́n ti wí pé: “Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a pa wọ́n rẹ́ kúrò ní jíjẹ́ orílẹ̀-èdè,+ Kí a má bàa rántí orúkọ Ísírẹ́lì mọ́.”+   Nítorí pé wọ́n ti fi ọkàn-àyà gbìmọ̀ pọ̀ ní ìsopọ̀ṣọ̀kan;+ Àní wọ́n tẹ̀ síwájú láti dá májẹ̀mú lòdì sí ọ,+   Àwọn àgọ́ Édómù+ àti ti àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì, Móábù+ àti ti àwọn ọmọ Hágárì,+   Gébálì àti Ámónì+ àti Ámálékì, Filísíà+ pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùgbé Tírè.+   Pẹ̀lúpẹ̀lù, Ásíríà alára ti dara pọ̀ mọ́ wọn;+ Wọ́n ti di apá kan ṣoṣo fún àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì.+ Sélà.   Ṣe wọ́n bí ti Mídíánì,+ bí ti Sísérà,+ Bí ti Jábínì+ ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kíṣónì.+ 10  A pa wọ́n rẹ́ ráúráú ní Ẹ́ń-dórì;+ Wọ́n di ajílẹ̀ fún ilẹ̀.+ 11  Ní ti àwọn ọ̀tọ̀kùlú wọn, ṣe àwọn wọ̀nyí bí Órébù àti bí Séébù,+ Àti bí Séébà àti bí Sálímúnà gbogbo àwọn mọ́gàjí wọn,+ 12  Tí wọ́n ti wí pé: “Ẹ jẹ́ kí a gba àwọn ibi gbígbé Ọlọ́run fún ara wa.”+ 13  Ìwọ Ọlọ́run mi, ṣe wọ́n bí òṣùṣú tí ààjà ń gbé kiri,+ Bí àgékù pòròpórò níwájú ẹ̀fúùfù.+ 14  Bí iná tí ń jó igbó+ Àti bí ọwọ́ iná tí ń jó àwọn òkè ńlá gbẹ,+ 15  Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni kí o fi ìjì líle rẹ lépa wọn,+ Kí o sì fi ẹ̀fúùfù rẹ oníjì yọ wọ́n lẹ́nu.+ 16  Fi àbùkù kún ojú wọn,+ Kí àwọn ènìyàn lè máa wá orúkọ rẹ, Jèhófà.+ 17  Kí ojú tì wọ́n, kí a sì yọ wọ́n lẹ́nu ní ìgbà gbogbo,+ Kí wọ́n sì tẹ́, kí wọ́n sì ṣègbé;+ 18  Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀+ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà,+ Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ+ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé