Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 82:1-8

Orin atunilára ti Ásáfù. 82  Ọlọ́run dúró nínú àpéjọ+ Olú Ọ̀run;+ Ó ń ṣe ìdájọ́ ní àárín àwọn ọlọ́run+ pé:   “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ óò máa fi àìṣèdájọ́ òdodo dáni lẹ́jọ́,+ Tí ẹ ó sì máa ṣe ojúsàájú àwọn ẹni burúkú?+ Sélà.   Ẹ jẹ́ onídàájọ́ fún ẹni rírẹlẹ̀ àti ọmọdékùnrin aláìníbaba.+ Ẹ ṣe ìdájọ́ òdodo fún ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti ẹni tí ó jẹ́ aláìnílọ́wọ́.+   Ẹ pèsè àsálà fún ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì;+ Ẹ dá wọn nídè kúrò ní ọwọ́ àwọn ẹni burúkú.”+   Wọn kò mọ̀, wọn kò sì lóye;+ Inú òkùnkùn ni wọ́n ti ń rìn káàkiri;+ Gbogbo ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé ni a mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n.+   “Èmi alára ti wí pé, ‘Ẹ̀yin jẹ́ ọlọ́run,+ Gbogbo yín sì jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ.+   Ṣe ni ẹ óò kú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn;+ Ẹ ó sì ṣubú bí èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ aládé!’”+   Dìde, Ọlọ́run, ṣe ìdájọ́ ilẹ̀ ayé;+ Nítorí pé ìwọ tìkára rẹ yóò gba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣe ìní.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé