Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 81:1-16

Sí olùdarí lórí Gítítì.+ Ti Ásáfù. 81  Ẹ fi ìdùnnú ké jáde sí Ọlọ́run okun wa;+Ẹ kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun sí Ọlọ́run Jékọ́bù.+   Ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin atunilára,+ kí ẹ sì gbé ìlù tanboríìnì,+Háàpù dídùn mọ́ni pẹ̀lú ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín.+   Nígbà òṣùpá tuntun, ẹ fun ìwo;+Nígbà òṣùpá àrànmọ́jú, nítorí ọjọ́ àjọyọ̀ wa.+   Nítorí pé ó jẹ́ ìlànà fún Ísírẹ́lì,+Ìpinnu ìdájọ́ ti Ọlọ́run Jékọ́bù.   Gẹ́gẹ́ bí ìránnilétí, ó gbé e kalẹ̀ fún Jósẹ́fù tìkára rẹ̀,+Nígbà tí ó ń jáde lọ lórí ilẹ̀ Íjíbítì.+Èdè tí èmi kò mọ̀ ni mo ń gbọ́.+   “Àní mo yí èjìká rẹ̀ kúrò lábẹ́ ẹrù ìnira;+Apẹ̀rẹ̀ pàápàá kò sí lọ́wọ́ rẹ̀ mọ́.+   Ìwọ pè nínú wàhálà, mo sì tẹ̀ síwájú láti gbà ọ́ sílẹ̀;+Mo bẹ̀rẹ̀ sí dá ọ lóhùn ní ibi lílùmọ́ ti ààrá.+Mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣàyẹ̀wò rẹ níbi omi Mẹ́ríbà.+ Sélà.   Ẹ gbọ́, ẹ̀yin ènìyàn mi, dájúdájú, èmi yóò jẹ́rìí lòdì sí yín,+Ísírẹ́lì, bí ìwọ yóò bá fetí sí mi.+   Kì yóò sí àjèjì ọlọ́run kankan láàárín yín;+Ẹ kì yóò sì tẹrí ba fún ọlọ́run ilẹ̀ òkèèrè.+ 10  Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ,+Ẹni tí ó mú ọ gòkè wá láti ilẹ̀ Íjíbítì.+La ẹnu rẹ gbayawu, èmi yóò sì kún un.+ 11  Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi kò fetí sí ohùn mi;+Àní Ísírẹ́lì kò fi ẹ̀mí ìmúratán hàn sí mi rárá.+ 12  Nítorí náà, mo jẹ́ kí wọ́n lọ nínú agídí ọkàn-àyà wọn;+Wọ́n ń rìn nínú ìmọ̀ràn ara wọn.+ 13  Ì bá ṣe pé àwọn ènìyàn mi fetí sí mi,+Ì bá ṣe pé Ísírẹ́lì alára rìn àní ní àwọn ọ̀nà mi!+ 14  Èmi ì bá tẹ àwọn ọ̀tá wọn lórí ba tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn,+Èmi ì bá sì yí ọwọ́ mi padà sí àwọn elénìní wọn.+ 15  Ní ti àwọn tí ó kórìíra Jèhófà lọ́nà gbígbóná janjan, wọn yóò wá fi ìwárìrì tẹrí ba fún un,+Ìgbà wọn yóò sì máa wà fún àkókò tí ó lọ kánrin. 16  Òun yóò sì máa bọ́ ọ láti inú ọ̀rá àlìkámà,+Láti inú àpáta ni èmi yóò sì ti fi oyin+ pàápàá tẹ́ ọ lọ́rùn.”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé