Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 80:1-19

Sí olùdarí lórí Òdòdó Lílì.+ Ìránnilétí. Ti Ásáfù.+ Orin atunilára. 80  Ìwọ Olùṣọ́ Àgùntàn Ísírẹ́lì, fi etí sílẹ̀,+Ìwọ tí ń darí Jósẹ́fù gẹ́gẹ́ bí agbo ẹran.+Ìwọ tí ń jókòó lórí àwọn kérúbù,+ kí o tàn yanran.+   Níwájú Éfúráímù àti Bẹ́ńjámínì àti Mánásè, gbé agbára ńlá rẹ dìde,+Kí o sì wá fún ìgbàlà wa.+   Ọlọ́run, mú wa padà wá;+Kí o sì mú kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ kedere, kí a lè gbà wá là.+   Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa bínú sí àdúrà àwọn ènìyàn rẹ?+   Ìwọ ti mú kí wọ́n jẹ oúnjẹ omijé,+O sì ń mú kí wọ́n máa mu omijé lé omijé ní ìwọ̀n púpọ̀.+   Ìwọ ti gbé wa kalẹ̀ fún gbọ́nmi-si omi-ò-to sí àwọn aládùúgbò wa,+Àní àwọn ọ̀tá wa ń fi wá ṣẹ̀sín ṣáá bí ó ṣe wù wọ́n.+   Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, mú wa padà wá;+Kí o sì mú kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ kedere, kí a lè gbà wá là.+   Ìwọ bẹ̀rẹ̀ sí mú kí àjàrà kan lọ kúrò ní Íjíbítì.+Ìwọ ń lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde, kí o lè gbìn ín.+   Ìwọ ṣán iwájú rẹ̀ mọ́,+ kí ó lè ta gbòǹgbò, kí ó sì kún ilẹ̀.+ 10  Òjìji rẹ̀ bo òkè ńláńlá mọ́lẹ̀,Àwọn ẹ̀tun rẹ̀ sì bo àwọn kédárì Ọlọ́run mọ́lẹ̀.+ 11  Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó yọ àwọn ẹ̀tun rẹ̀ jáde títí dé òkun,+Àti àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀ títí dé Odò.+ 12  Èé ṣe tí ìwọ fi wó ògiri òkúta rẹ̀ lulẹ̀,+Èé sì ti ṣe tí gbogbo àwọn tí ń kọjá lọ lójú ọ̀nà fi ń já a?+ 13  Ìmàdò inú ẹgàn ń jẹ ẹ́,+Ògídímèje àwọn ẹran pápá gbalasa sì ń fi í ṣe oúnjẹ jẹ.+ 14  Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, jọ̀wọ́, padà;+Bojú wolẹ̀ láti ọ̀run, kí o sì rí i, kí o sì bójú tó àjàrà yìí,+ 15  Àti kùkùté igi tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ti gbìn,+Kí o sì wo ọmọ tí ìwọ ti sọ di alágbára fún ara rẹ.+ 16  A ti fi iná sun ún, a ké e kúrò.+Wọ́n ṣègbé nípa ìbáwí mímúná ojú rẹ.+ 17  Jẹ́ kí ọwọ́ rẹ wà lára ọkùnrin ọwọ́ ọ̀tún rẹ,+Lára ọmọ aráyé tí ìwọ ti sọ di alágbára fún ara rẹ,+ 18  Àwa kì yóò sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ rẹ.+Kí o pa wá mọ́ láàyè, kí a lè máa ké pe orúkọ rẹ.+ 19  Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, mú wa padà wá;+Mú kí ojú rẹ mọ́lẹ̀ kedere, kí a lè gbà wá là.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé