Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 8:1-9

Sí olùdarí lórí Gítítì.+ Orin atunilára ti Dáfídì. 8  Ìwọ Jèhófà Olúwa wa, orúkọ rẹ mà kún fún ọlá ńlá ní gbogbo ilẹ̀ ayé o,+ Ìwọ tí a ń ròyìn iyì rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ lókè ọ̀run!+   Láti ẹnu àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ẹnu ọmú ni o ti fi ìpìlẹ̀ okun sọlẹ̀,+ Ní tìtorí àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí ọ,+ Láti lè mú kí ọ̀tá àti ẹni tí ń gbẹ̀san jáwọ́.+   Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ,+ Òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀,+   Kí ni ẹni kíkú+ tí o fi ń fi í sọ́kàn,+ Àti ọmọ ará ayé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?+   Ìwọ sì tẹ̀ síwájú láti ṣe é ní ẹni rírẹlẹ̀ díẹ̀ ju àwọn ẹni bí Ọlọ́run,+ O sì wá fi ògo+ àti ọlá ńlá dé e ládé.+   O mú kí ó jọba lé àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ;+ O ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀:+   Àwọn ẹran ọ̀sìn kéékèèké àti màlúù, gbogbo wọn,+ Àti àwọn ẹranko pápá gbalasa pẹ̀lú,+   Àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹja inú òkun,+ Ohunkóhun tí ń la àwọn ipa ọ̀nà òkun kọjá.+   Ìwọ Jèhófà Olúwa wa, orúkọ rẹ mà kún fún ọlá ńlá ní gbogbo ilẹ̀ ayé o!+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé