Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 79:1-13

Orin atunilára ti Ásáfù. 79  Ọlọ́run, àwọn orílẹ̀-èdè ti wá sínú ogún rẹ;+ Wọ́n ti sọ tẹ́ńpìlì mímọ́ rẹ di ẹlẹ́gbin;+ Wọ́n ti sọ Jerúsálẹ́mù di òkìtì àwókù.+   Wọ́n ti fi òkú àwọn ìránṣẹ́ rẹ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá abìyẹ́ ojú ọ̀run,+ Wọ́n ti fi ẹran ara àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ fún àwọn ẹranko ilẹ̀ ayé.+   Wọ́n ti da ẹ̀jẹ̀ wọn jáde bí omi Ní gbogbo àyíká Jerúsálẹ́mù, kò sì sí ẹnì kankan láti sìnkú.+   Àwa ti di ẹ̀gàn fún àwọn aládùúgbò wa,+ Ẹni ìfiṣẹ̀sín àti ìfiṣeyẹ̀yẹ́ fún àwọn tí ó wà yí wa ká.+   Yóò ti pẹ́ tó, Jèhófà, tí ìbínú rẹ yóò máa ru sókè? Ṣé títí láé ni?+ Yóò ti pẹ́ tó tí ìgbóná-ọkàn rẹ yóò máa jó gẹ́gẹ́ bí iná?+   Da ìhónú rẹ sórí àwọn orílẹ̀-èdè tí kò mọ̀ ọ́,+ Àti sórí àwọn ìjọba tí kò ké pe orúkọ rẹ.+   Nítorí pé wọ́n ti jẹ Jékọ́bù run,+ Wọ́n sì ti mú kí ibi gbígbé rẹ̀ di ahoro.+   Má ṣe rántí ìṣìnà àwọn baba ńlá wa ìgbàanì sí wa.+ Ṣe wéré! Jẹ́ kí àánú rẹ bá wa pàdé,+ Nítorí pé a ti di òtòṣì gidigidi.+   Ràn wá lọ́wọ́, ìwọ Ọlọ́run ìgbàlà wa,+ Nítorí ògo orúkọ rẹ;+ Kí o sì dá wa nídè, kí o sì bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa ní tìtorí orúkọ rẹ.+ 10  Èé ṣe tí àwọn orílẹ̀-èdè yóò fi sọ pé: “Ọlọ́run wọn dà?”+ Láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, jẹ́ kí ó di mímọ̀ lójú wa,+ Ìgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí a ti ta sílẹ̀.+ 11  Kí ìmí ẹ̀dùn ẹlẹ́wọ̀n wọlé wá àní síwájú rẹ.+ Gẹ́gẹ́ bí títóbi apá rẹ, pa àwọn tí a yàn kalẹ̀ fún ikú mọ́.+ 12  Kí o sì san án padà fún àwọn aládùúgbò wa ní ìgbà méje sí oókan àyà wọn,+ Ẹ̀gàn wọn tí wọ́n ti fi gàn ọ́, Jèhófà.+ 13  Ní ti àwa ènìyàn rẹ àti agbo ẹran pápá ìjẹko rẹ,+ Àwa yóò máa fi ọpẹ́ fún ọ dé àkókò tí ó lọ kánrin; Láti ìran dé ìran ni àwa yóò máa polongo ìyìn rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé