Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 78:1-72

Másíkílì. Ti Ásáfù.+ 78  Ẹ fi etí sí òfin mi, ẹ̀yin ènìyàn mi;+ Ẹ dẹ etí sí àwọn àsọjáde ẹnu mi.+   Ṣe ni èmi yóò la ẹnu mi nínú ọ̀rọ̀ òwe;+ Èmi yóò sì mú kí àwọn àlọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn tú jáde,+   Èyí tí a ti gbọ́ tí a sì mọ̀,+ Èyí tí àwọn baba wa sì ti ṣèròyìn fún wa;+   Èyí tí àwa kò fi pa mọ́ fún àwọn ọmọ wọn,+ Tí a ń ṣèròyìn wọn àní fún ìran tí ń bọ̀,+ Ìyìn Jèhófà àti okun rẹ̀+ Àti àwọn ohun àgbàyanu rẹ̀ tí ó ti ṣe.+   Ó sì tẹ̀ síwájú láti gbé ìránnilétí kan dìde ní Jékọ́bù,+ Ó sì gbé òfin kan kalẹ̀ ní Ísírẹ́lì,+ Àwọn ohun tí ó pa láṣẹ fún àwọn baba ńlá wa,+ Pé kí wọ́n sọ ọ́ di mímọ̀ fún àwọn ọmọ wọn;+   Kí ìran tí ń bọ̀, àwọn ọmọ tí a óò bí, lè mọ̀ wọ́n,+ Kí wọ́n lè dìde, kí wọ́n sì ṣèròyìn wọn fún àwọn ọmọ wọn,+   Kí wọ́n sì lè gbé ìgbọ́kànlé wọn ka Ọlọ́run tìkára rẹ̀,+ Kí wọ́n má sì gbàgbé àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run,+ bí kò ṣe pé kí wọ́n máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.+   Kí wọ́n má sì dà bí àwọn baba ńlá wọn,+ Ìran alágídí àti ọlọ̀tẹ̀,+ Ìran tí kò múra ọkàn-àyà wọn sílẹ̀,+ Tí ẹ̀mí wọn kò sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé níwájú Ọlọ́run.+   Àwọn ọmọ Éfúráímù, bí wọ́n tilẹ̀ jẹ́ olùta ọrun tí ó ti dìhámọ́ra,+ Sá padà ní ọjọ́ ìjà.+ 10  Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́,+ Wọ́n sì kọ̀ láti máa rìn nínú òfin rẹ̀.+ 11  Wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ sí gbàgbé ìbálò rẹ̀+ Àti àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ tí ó jẹ́ kí wọ́n rí.+ 12  Ó ṣe ohun ìyanu ní iwájú àwọn baba ńlá wọn+ Ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ àní pápá Sóánì.+ 13  Ó pín òkun níyà, kí ó lè jẹ́ kí wọ́n ré kọjá,+ Ó sì mú kí omi dúró bí ìsédò.+ 14  Ó ń bá a lọ ní fífi àwọsánmà ṣamọ̀nà wọn ní ọ̀sán+ Àti ìmọ́lẹ̀ iná ní gbogbo òru.+ 15  Ó tẹ̀ síwájú láti la àpáta ní aginjù,+ Kí ó lè mú kí wọ́n mu ọ̀pọ̀ yanturu gẹ́gẹ́ bí ibú omi.+ 16  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú ìṣàn omi jáde wá láti inú àpáta gàǹgà,+ Ó sì ń mú kí omi ṣàn gẹ́gẹ́ bí àwọn odò.+ 17  Wọ́n sì tún ń bá a nìṣó ní títúbọ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí i,+ Nípa ṣíṣọ̀tẹ̀ sí Ẹni Gíga Jù Lọ ní ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi;+ 18  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dán Ọlọ́run wò nínú ọkàn-àyà wọn,+ Nípa bíbéèrè fún nǹkan jíjẹ fún ọkàn wọn.+ 19  Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ sí Ọlọ́run.+ Wọ́n wí pé: “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì nínú aginjù bí?”+ 20  Wò ó! Ó lu àpáta,+ Kí omi lè ṣàn, kí àwọn ọ̀gbàrá sì lè ya jáde.+ “Ó ha lè fúnni ní oúnjẹ pẹ̀lú bí,+ Tàbí ó ha lè pèsè ohun ìgbẹ́mìíró sílẹ̀ fún àwọn ènìyàn rẹ̀?”+ 21  Ìdí nìyẹn tí Jèhófà fi gbọ́, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bínú kíkankíkan;+ A sì mú kí iná jó Jékọ́bù,+ Ìbínú sì ru sí Ísírẹ́lì pẹ̀lú.+ 22  Nítorí tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run,+ Wọn kò sì gbẹ́kẹ̀ lé ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.+ 23  Ó sì tẹ̀ síwájú láti pàṣẹ fún sánmà ṣíṣú dẹ̀dẹ̀ lókè, Àní ó ṣí àwọn ilẹ̀kùn ọ̀run.+ 24  Ó sì ń rọ̀jò mánà lé wọn lórí ṣáá láti jẹ,+ Ó sì fún wọn ní ọkà ọ̀run.+ 25  Àní àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn alágbára;+ Ó fi ìpèsè oúnjẹ ránṣẹ́ sí wọn tẹ́rùntẹ́rùn.+ 26  Ó bẹ̀rẹ̀ sí mú kí ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn rọ́ jáde ní ọ̀run,+ Ó sì mú kí ẹ̀fúùfù gúúsù fẹ́ nípasẹ̀ okun tirẹ̀.+ 27  Ó sì tẹ̀ síwájú láti mú kí ohun ìgbẹ́mìíró rọ̀ lé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí ekuru,+ Àní àwọn ẹ̀dá abìyẹ́lápá tí ń fò, gẹ́gẹ́ bí àwọn egunrín iyanrìn òkun.+ 28  Ó sì ń bá a nìṣó ní mímú kí wọ́n bọ́ sí àárín ibùdó rẹ̀,+ Ní gbogbo àyíká àwọn àgọ́ rẹ̀.+ 29  Wọ́n sì ń jẹ, wọ́n sì ń tẹ́ ara wọn lọ́rùn gidigidi,+ Ohun tí wọ́n ní ìfẹ́-ọkàn sí ni ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú wá fún wọn.+ 30  Wọn kò yí padà kúrò nínú ìfẹ́-ọkàn wọn, Nígbà tí oúnjẹ wọ́n ṣì wà ní ẹnu wọn,+ 31  Nígbà tí ìrunú Ọlọ́run ru sí wọn,+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí pa lára àwọn tí ó táagun nínú wọn;+ Ó sì mú kí àwọn ọ̀dọ́kùnrin Ísírẹ́lì wó lulẹ̀. 32  Láìka gbogbo èyí sí, ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń dẹ́ṣẹ̀,+ Wọn kò sì ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀.+ 33  Nítorí náà, ó mú ọjọ́ wọn wá sí òpin bí èémí àmíjáde lásán-làsàn,+ Àti ọdún wọn nípa ìyọlẹ́nu. 34  Nígbàkúùgbà tí ó bá pa wọ́n, àwọn pẹ̀lú a ṣe ìwádìí nípa rẹ̀,+ Wọn a sì padà, wọn a sì wá Ọlọ́run.+ 35  Wọ́n a sì bẹ̀rẹ̀ sí rántí pé Ọlọ́run ni Àpáta wọn,+ Àti pé Ọlọ́run tí í ṣe Ẹni Gíga Jù Lọ ni Olùgbẹ̀san wọn.+ 36  Wọ́n sì gbìyànjú láti fi ẹnu wọn tàn án;+ Wọ́n sì gbìyànjú láti fi ahọ́n wọn purọ́ fún un.+ 37  Ọkàn-àyà wọn kò sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin lọ́dọ̀ rẹ̀;+ Wọn kò sì jẹ́ aṣeégbíyèlé nínú májẹ̀mú rẹ̀.+ 38  Ṣùgbọ́n ó jẹ́ aláàánú;+ òun a sì bo ìṣìnà+ náà, kì yóò sì mú ìparun wá.+ Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó sì mú kí ìbínú rẹ̀ yí padà,+ Kì í sì í ru gbogbo ìhónú rẹ̀ dìde. 39  Ó sì ń bá a nìṣó ní rírántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n,+ Pé ẹ̀mí ń jáde lọ, kì í sì í padà wá.+ 40  Ẹ wo bí iye ìgbà tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù ti pọ̀ tó,+ Wọn a máa mú kí inú rẹ̀ bàjẹ́ ní aṣálẹ̀!+ 41  Léraléra ni wọ́n sì ń dán Ọlọ́run wò,+ Àní wọ́n ṣe ohun tí ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+ 42  Wọn kò rántí ọwọ́ rẹ̀,+ Ní ọjọ́ tí ó tún wọn rà padà láti ọwọ́ elénìní,+ 43  Bí ó ṣe fi àwọn iṣẹ́ àmì rẹ̀ sí Íjíbítì+ Àti àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sí pápá Sóánì;+ 44  Àti bí ó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí sọ àwọn ipa odò Náílì wọn di ẹ̀jẹ̀,+ Tí wọn kò fi lè mu láti inú àwọn ìṣàn omi tiwọn.+ 45  Ó sì tẹ̀ síwájú láti rán àwọn eṣinṣin mùjẹ̀mùjẹ̀ sí wọn, kí ìwọ̀nyí lè jẹ wọ́n run;+ Àti àwọn àkèré, kí ìwọ̀nyí lè run wọ́n.+ 46  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi èso wọn fún aáyán, Àti làálàá wọn fún eéṣú.+ 47  Àní ó bẹ̀rẹ̀ sí fi yìnyín pa àjàrà wọn,+ Ó sì fi àwọn òkúta yìnyín pa àwọn igi síkámórè wọn.+ 48  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ẹranko arẹrù wọn lé yìnyín lọ́wọ́,+ Àti ohun ọ̀sìn wọn fún ibà amáragbóná fòfò. 49  Ó ń bá a lọ ní rírán ìbínú rẹ̀ jíjófòfò sórí wọn,+ Ìbínú kíkan àti ìdálẹ́bi àti wàhálà,+ Àwùjọ àwọn áńgẹ́lì tí a rán láti mú ìyọnu àjálù wá.+ 50  Ó tẹ̀ síwájú láti pèsè ipa ọ̀nà sílẹ̀ fún ìbínú rẹ̀.+ Kò fa ọkàn wọn sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ ikú; Ó sì fi ìwàláàyè wọn lé àjàkálẹ̀ àrùn lọ́wọ́.+ 51  Níkẹyìn, ó ṣá gbogbo àkọ́bí balẹ̀ ní Íjíbítì,+ Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ agbára ìbímọ wọn nínú àwọn àgọ́ Hámù.+ 52  Lẹ́yìn ìgbà náà, ó mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde lọ gẹ́gẹ́ bí agbo ẹran kan,+ Ó sì darí wọn bí agbo ẹran ọ̀sìn kan ní aginjù.+ 53  Ó sì ń ṣamọ̀nà wọn nínú ààbò, wọn kò sì ní ìbẹ̀rùbojo;+ Òkun sì bo àwọn ọ̀tá wọn.+ 54  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mú wọn wá sí ìpínlẹ̀ mímọ́ rẹ̀,+ Ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá yìí, tí ó jẹ́ pé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni ó ni ín.+ 55  Àti nítorí wọn, ó lé àwọn orílẹ̀-èdè jáde ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀,+ Ó sì ń bá a lọ láti fi okùn ìdiwọ̀n pín ogún fún wọn,+ Tí ó fi mú kí àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì máa gbé inú ilé tiwọn.+ 56  Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí dán Ọlọ́run tí í ṣe Ẹni Gíga Jù Lọ wò, wọ́n sì ṣọ̀tẹ̀ sí i,+ Wọn kò sì pa àwọn ìránnilétí rẹ̀ mọ́.+ 57  Pẹ̀lúpẹ̀lù, wọ́n ń yí padà ṣáá, wọ́n sì ń hùwà lọ́nà àdàkàdekè bí àwọn baba ńlá wọn;+ Wọ́n yíjú padà bí ọrun dídẹ̀.+ 58  Wọ́n sì ń fi àwọn ibi gíga wọn mú un bínú ṣáá,+ Wọ́n sì ń fi àwọn ère fífín wọn ru ú lọ́kàn sókè sí owú ṣáá.+ 59  Ọlọ́run gbọ́,+ ó sì bínú kíkankíkan,+ Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fojú pa Ísírẹ́lì rẹ́ gidigidi.+ 60  Níkẹyìn, ó sì ṣá àgọ́ ìjọsìn Ṣílò tì,+ Àgọ́ tí ó ń gbé inú rẹ̀ láàárín ará ayé.+ 61  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi okun rẹ̀ fún oko òǹdè pàápàá,+ Ó sì fi ẹwà rẹ̀ lé elénìní lọ́wọ́.+ 62  Ó sì ń fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́,+ Ó sì bínú kíkankíkan sí ogún rẹ̀.+ 63  Iná jẹ àwọn ọ̀dọ́kùnrin rẹ̀ run, A kò sì fi ìyìn fún àwọn wúńdíá rẹ̀.+ 64  Ní ti àwọn àlùfáà rẹ̀, wọ́n tipa idà ṣubú,+ Àwọn opó wọn kò sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún.+ 65  Nígbà náà ni Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí jí bí ẹni pé kúrò lójú oorun,+ Bí alágbára ńlá tí ọtí wáínì ń dá lójú rẹ̀.+ 66  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣá àwọn elénìní rẹ̀ balẹ̀ láti ẹ̀yìn;+ Ẹ̀gàn tí ó wà fún àkókò tí ó lọ kánrin ni ó kó bá wọn.+ 67  Ó sì tẹ̀ síwájú láti kọ àgọ́ Jósẹ́fù;+ Kò sì yan ẹ̀yà Éfúráímù.+ 68  Ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà Júdà,+ Òkè Ńlá Síónì, èyí tí òun nífẹ̀ẹ́.+ 69  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ibùjọsìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ibi gíga,+ Bí ilẹ̀ ayé tí ó ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 70  Ó sì tipa bẹ́ẹ̀ yan Dáfídì ìránṣẹ́ rẹ̀,+ Ó sì mú un kúrò nínú àwọn ọgbà agbo ẹran.+ 71  Kúrò ní títọ àwọn abo tí ń fọ́mọ lọ́mú lẹ́yìn,+ Ó mú un wá láti jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn lórí Jékọ́bù ènìyàn rẹ̀+ Àti lórí Ísírẹ́lì ogún rẹ̀.+ 72  Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe olùṣọ́ àgùntàn wọn ní ìbámu pẹ̀lú ìwà títọ́ ọkàn-àyà rẹ̀,+ Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìjáfáfá ọwọ́ rẹ̀ ṣamọ̀nà wọn.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé