Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 77:1-20

Sí olùdarí lórí Jédútúnì. Ti Ásáfù.+ Orin atunilára. 77  Àní èmi yóò fi ohùn mi ké jáde sí Ọlọ́run tìkára rẹ̀,+Èmi yóò fi ohùn mi ké pe Ọlọ́run, dájúdájú, òun yóò fi etí sí mi.+   Ní ọjọ́ wàhálà mi, mo wá Jèhófà tìkára rẹ̀.+Àní ọwọ́ mi ti nà jáde ní òru, kò sì kú tipiri;Ọkàn mi ti kọ̀ láti gba ìtùnú.+   Ṣe ni èmi yóò rántí Ọlọ́run, èmi yóò sì di aláriwo líle;+Èmi yóò fi ìdàníyàn hàn, kí ẹ̀mí mi lè di aláìlókun.+ Sélà.   Ìwọ ti gbá ìpéǹpéjú mi mú;+Ṣìbáṣìbo ti bá mi, èmi kò sì lè sọ̀rọ̀.+   Èmi ti ronú nípa àwọn ọjọ́ ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn,+Nípa àwọn ọdún tí ó ti kọjá tipẹ́tipẹ́.   Ṣe ni èmi yóò rántí orin tí mo fi ohun èlò olókùn tín-ín-rín kọ ní òru;+Èmi yóò fi ìdàníyàn hàn nínú ọkàn-àyà mi,+Ẹ̀mí mi yóò sì fẹ̀sọ̀ ṣe ìwákiri.   Ṣé fún àkókò tí ó lọ kánrin ni Jèhófà yóò máa tani nù,+Ṣé òun kì yóò tún ní ìtẹ́lọ́rùn mọ́ ni?+   Ṣé inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ ti kásẹ̀ nílẹ̀ títí láé ni?+Ṣé àsọjáde rẹ̀ ti di asán+ láti ìran dé ìran ni?   Ṣé Ọlọ́run ti gbàgbé láti ṣe ojú rere ni,+Tàbí kẹ̀, ṣé ó ti fi ìbínú sé àánú rẹ̀ mọ́ ni?+ Sélà. 10  Ṣé kí n sì máa wí ṣáá pé: “Èyí ni ohun tí ń gún mi ní àgúnyọ,+Ìyípadà ọwọ́ ọ̀tún Ẹni Gíga Jù Lọ”?+ 11  Èmi yóò rántí àwọn iṣẹ́ Jáà;+Nítorí ó dájú pé èmi yóò rántí ìṣe ìyanu rẹ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn.+ 12  Dájúdájú, èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ,+Ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.+ 13  Ọlọ́run, ọ̀nà rẹ wà ní ibi mímọ́.+Ta ni Ọlọ́run ńlá bí Ọlọ́run?+ 14  Ìwọ ni Ọlọ́run tòótọ́, tí ń ṣe ohun ìyanu.+Ìwọ ti sọ okun rẹ di mímọ̀ láàárín àwọn ènìyàn.+ 15  Ìwọ ti fi apá rẹ mú àwọn ènìyàn rẹ padà,+Àwọn ọmọ Jékọ́bù àti ti Jósẹ́fù. Sélà. 16  Omi rí ọ, Ọlọ́run,Omi rí ọ; ó bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ìrora mímúná.+Pẹ̀lúpẹ̀lù, ṣìbáṣìbo bẹ̀rẹ̀ sí bá ibú omi.+ 17  Àwọsánmà ti fi sísán ààrá da omi sílẹ̀;+Sánmà ṣíṣú dẹ̀dẹ̀ ti mú ìró jáde.Pẹ̀lúpẹ̀lù, àwọn ọfà rẹ bẹ̀rẹ̀ sí lọ síhìn-ín sọ́hùn-ún.+ 18  Ìró ààrá rẹ dà bí àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ ẹṣin;+Mànàmáná ti mú ilẹ̀ eléso mọ́lẹ̀ kedere;+Ṣìbáṣìbo bá ilẹ̀ ayé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí mì jìgìjìgì.+ 19  Ọ̀nà rẹ gba inú òkun kọjá,+Ipa ọ̀nà rẹ sì gba inú omi púpọ̀ kọjá;A kò sì wá mọ àwọn ojú ẹsẹ̀ rẹ. 20  Ìwọ ti ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn rẹ gẹ́gẹ́ bí agbo ẹran kan,+Nípa ọwọ́ Mósè àti Áárónì.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé