Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 76:1-12

Sí olùdarí tí ń lo àwọn ohun èlò ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Orin atunilára. Ti Ásáfù.+ Orin. 76  A mọ Ọlọ́run ní Júdà;+Orúkọ rẹ̀ tóbi ní Ísírẹ́lì.+   Ibi kọ́lọ́fín rẹ̀ sì wà ní Sálẹ́mù,+Ibi gbígbé rẹ̀ sì wà ní Síónì.+   Ibẹ̀ ni ó ti ṣẹ́ àwọn ẹ̀rú ọrun tí ń kọná yẹ̀rì,+Apata àti idà àti ìjà ogun.+ Sélà.   Ìmọ́lẹ̀ ni ó bò ọ́ yí ká, ìwọ jẹ́ ọlọ́lá ńlá ju àwọn òkè ńlá tí ó ní ẹran ọdẹ.+   Àwọn alágbára ní ọkàn-àyà ni a ti fi ṣe ìjẹ,+Wọ́n ti tòògbé títí oorun fi gbé wọn lọ,+Kò sì sí ìkankan lára gbogbo àwọn akíkanjú tí ó rí ọwọ́ wọn.+   Nípa ìbáwí mímúná rẹ, Ọlọ́run Jékọ́bù, àti oníkẹ̀kẹ́ ẹṣin àti ẹṣin ti sùn lọ fọnfọn.+   Ìwọ—amúnikún-fún-ẹ̀rù ni ìwọ,+Ta sì ni ó lè dúró níwájú rẹ nítorí okun ìbínú rẹ?+   Láti ọ̀run, ìwọ mú kí a gbọ́ ìfagagbága lábẹ́ òfin;+Ilẹ̀ ayé pàápàá bẹ̀rù, ó sì gbé jẹ́ẹ́+   Nígbà tí Ọlọ́run dìde sí ìdájọ́,+Láti gba gbogbo àwọn ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé là.+ Sélà. 10  Nítorí pé àní ìhónú ènìyàn yóò gbé ọ lárugẹ;+Ìyókù ìhónú ni ìwọ yóò fi di ara rẹ lámùrè. 11  Ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́, kí ẹ sì san án fún Jèhófà Ọlọ́run yín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ yí i ká.+Kí wọ́n fi ìbẹ̀rù mú ẹ̀bùn wá.+ 12  Òun yóò rẹ ẹ̀mí àwọn aṣáájú sílẹ̀;+Amúnikún-fún-ẹ̀rù ni òun jẹ́ sí àwọn ọba ilẹ̀ ayé.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé