Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 75:1-10

Sí olùdarí. “Má ṣe run ún.” Orin atunilára. Ti Ásáfù.+ Orin. 75  Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Ọlọ́run; àwa fi ọpẹ́ fún ọ,+Orúkọ rẹ sì ń bẹ nítòsí.+Ó dájú pé àwọn ènìyàn yóò máa polongo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+   “Nítorí tí mo tẹ̀ síwájú láti dá àkókò kan;+Èmi tìkára mi sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ìdúróṣánṣán ṣe ìdájọ́.+   Ilẹ̀ ayé àti gbogbo olùgbé inú rẹ̀ di yíyọ́,+Èmi ni mo mú àwọn ọwọ̀n rẹ̀ bọ̀ sípò.”+ Sélà.   Mo wí fún àwọn òmùgọ̀ pé: “Ẹ má ya òmùgọ̀,”+Àti fún àwọn ẹni burúkú pé: “Ẹ má ṣe gbé ìwo ga.+   Ẹ má ṣe gbé ìwo yín ga sí ibi gíga lókè.Ẹ má fi ọrùn ìṣefọ́nńté sọ̀rọ̀.+   Nítorí pé kì í ṣe láti ìlà-oòrùn tàbí láti ìwọ̀-oòrùn,Tàbí láti gúúsù ni ìgbéga ti ń wá.   Nítorí pé Ọlọ́run ni onídàájọ́.+Ẹni yìí ni ó rẹ̀ wálẹ̀, ẹni yẹn sì ni ó gbé ga.+   Nítorí pé ife kan wà ní ọwọ́ Jèhófà,+Wáìnì sì ń yọ ìfófòó, ó kún fún àdàlù.Dájúdájú, òun yóò da gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀ kúrò nínú rẹ̀;Gbogbo àwọn ẹni burúkú ilẹ̀ ayé yóò fà á gbẹ, wọn yóò mu ún.”+   Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa sọ nípa rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin;Ṣe ni èmi yóò máa kọ orin atunilára sí Ọlọ́run Jékọ́bù.+ 10  Gbogbo ìwo àwọn ẹni burúkú ni èmi yóò sì ké lulẹ̀.+Àwọn ìwo olódodo ni a óò gbé ga.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé