Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 74:1-23

Másíkílì. Ti Ásáfù.+ 74  Ọlọ́run, èé ṣe tí ìwọ fi ta wá nù títí láé?+ Èé ṣe tí ìbínú rẹ fi ń rú èéfín sí agbo ẹran pápá ìjẹko rẹ?+   Rántí àpéjọ rẹ tí ìwọ ti ní láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn,+ Ẹ̀yà tí ìwọ tún rà padà gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ,+ Òkè Ńlá Síónì yìí, nínú eyí tí ìwọ ń gbé.+   Gbé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ sókè sí àwọn ibi ìsọdahoro wíwà pẹ́ títí.+ Ohun gbogbo tí ọ̀tá ti ṣe láburú sí ní ibi mímọ́.+   Àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí ọ ti ké ramúramù ní àárín ibi ìpàdé rẹ.+ Wọ́n ti gbé àwọn àmì tiwọn kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àmì.+   Ẹnì kan jẹ́ olókìkí burúkú ní dídà bí ẹni tí ó gbé àáké sókè sí ìgbòrò tí ó kún fún igi.   Wàyí o, àní àwọn iṣẹ́ ọ̀nà fífín rẹ̀, gbogbo wọn lọ́kọ̀ọ̀kan, ni wọ́n fi àgègé àti àwọn ìtì onírin lórí kọlù.+   Wọ́n ti gbé ibùjọsìn rẹ sínú iná.+ Wọ́n ti sọ àgọ́ ìjọsìn orúkọ rẹ di aláìmọ́ títí dé ilẹ̀yílẹ̀.+   Àwọn, àní àwọn ọmọ wọn, ti jùmọ̀ wí nínú ọkàn-àyà wọn pé: “Gbogbo ibi ìpàdé Ọlọ́run ni a ó sun ní ilẹ̀ náà.”+   Àwa kò rí àwọn àmì wa; kò sí wòlíì kankan mọ́,+ Kò sì sí ẹnì kankan nínú wa tí ó mọ bí yóò ti pẹ́ tó. 10  Yóò ti pẹ́ tó, Ọlọ́run, tí elénìní yóò máa pẹ̀gàn?+ Ọ̀tá yóò ha máa hùwà àìlọ́wọ̀ sí orúkọ rẹ títí láé?+ 11  Èé ṣe tí ìwọ fi fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn, àní ọwọ́ ọ̀tún rẹ+ Kúrò ní àárín oókan àyà rẹ láti fi òpin sí wa? 12  Síbẹ̀síbẹ̀, Ọlọ́run ni Ọba mi láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn,+ Ẹni tí ń ṣe ìgbàlà títóbi lọ́lá ní àárín ilẹ̀ ayé.+ 13  Ìwọ tìkára rẹ ni ó fi okun rẹ ru òkun sókè;+ Ìwọ fọ́ orí àwọn ẹran ńlá abàmì inú òkun nínú omi.+ 14  Ìwọ tìkára rẹ ni ó fọ́ orí Léfíátánì+ sí wẹ́wẹ́. Ìwọ tẹ̀ síwájú láti fi í ṣe oúnjẹ fún àwọn ènìyàn, fún àwọn tí ń gbé àwọn ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi.+ 15  Ìwọ ni Ẹni tí ó pín ìsun àti ọ̀gbàrá níyà;+ Ìwọ tìkára rẹ ni ó mú odò tí ń ṣàn nígbà gbogbo gbẹ táútáú.+ 16  Tìrẹ ni ọ̀sán; tìrẹ ni òru pẹ̀lú.+ Ìwọ tìkára rẹ ni ó pèsè orísun ìmọ́lẹ̀ sílẹ̀, àní oòrùn.+ 17  Ìwọ ni ó pa gbogbo ààlà ilẹ̀ ayé;+ Ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù—ìwọ tìkára rẹ ni ó ṣẹ̀dá wọn.+ 18  Rántí èyí: Ọ̀tá ti pẹ̀gàn, Jèhófà,+ Àwọn òpònú ènìyàn sì ti hùwà àìlọ́wọ̀ sí orúkọ rẹ.+ 19  Má fi ọkàn oriri+ rẹ fún ẹranko ẹhànnà. Má gbàgbé títí láé, àní ìwàláàyè ẹni tìrẹ tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.+ 20  Wo májẹ̀mú,+ Nítorí pé àwọn ibi tí ó ṣókùnkùn ní ilẹ̀ ayé ti kún fún ibùjókòó ìwà ipá.+ 21  Kí ẹni tí a ni lára má padà wá ní ẹni tí a tẹ́ lógo.+ Kí ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àti òtòṣì máa yin orúkọ rẹ.+ 22  Dìde, Ọlọ́run, dá ẹjọ́ tìrẹ lábẹ́ òfin.+ Rántí ẹ̀gàn tí òpònú ń kó bá ọ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+ 23  Má gbàgbé ohùn àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí ọ.+ Ariwo àwọn tí ń dìde sí ọ ń gòkè nígbà gbogbo.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé