Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 73:1-28

Orin atunilára ti Ásáfù.+ 73  Ní tòótọ́, Ọlọ́run ṣe rere fún Ísírẹ́lì, fún àwọn tí ó mọ́ ní ọkàn-àyà.+   Ní tèmi, ẹsẹ̀ mi fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lọ́nà,+ Díẹ̀ ló kù kí a mú ìṣísẹ̀ mi yọ̀ tẹ̀rẹ́.+   Nítorí ti èmi ṣe ìlara àwọn aṣògo,+ Nígbà tí mo rí àlàáfíà àwọn ènìyàn burúkú.+   Nítorí tí wọn kì í ní ìroragógó ikú;+ Ikùn bẹ̀ǹbẹ̀ wọn sì yọ.+   Wọn kò tilẹ̀ sí nínú ìdààmú ẹni kíkú,+ Ìyọnu kì í sì í bá wọn bí ti àwọn ènìyàn mìíràn.+   Nítorí náà ni ìrera fi dà bí ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn fún wọn;+ Ìwà ipá bò wọ́n kanlẹ̀ bí ẹ̀wù.+   Ojú wọn yọ jáde fún ìsanra;+ Wọ́n ti ré kọjá ààlà ohun tí ọkàn-àyà lè rò.+   Wọ́n ń fini rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó burú;+ Wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa jìbìtì lọ́nà ìfẹgẹ̀.+   Wọ́n ti gbé ẹnu wọn àní sí ọ̀run,+ Ahọ́n wọn pàápàá sì ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ ayé.+ 10  Nítorí náà, ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ padà wá sí ìhín, A sì ń gbọ́n omi ohun tí ó kún fún wọn. 11  Wọ́n sì ti wí pé: “Báwo wá ni Ọlọ́run ṣe mọ̀?+ Ìmọ̀ ha sì wà nínú Ẹni Gíga Jù Lọ bí?”+ 12  Wò ó! Àwọn wọ̀nyí ni ẹni burúkú, àwọn tí ó wà ní ìdẹ̀rùn fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ Wọ́n ti mú kí àlùmọ́ọ́nì ìgbọ́bùkátà wọn pọ̀ sí i.+ 13  Dájúdájú, lásán ni mo wẹ ọkàn-àyà mi mọ́,+ Tí mo sì wẹ ọwọ́ mi ní àìmọwọ́mẹsẹ̀.+ 14  Ìyọnu sì ń bá mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀,+ Mo sì ń gba ìbáwí àfitọ́nisọ́nà ní òròòwúrọ̀.+ 15  Ká ní mo ti wí pé: “Ṣe ni èmi yóò sọ irú ìtàn bẹ́ẹ̀,” Wò ó! ìran àwọn ọmọ rẹ Ni èmi ì bá ti hùwà lọ́nà àdàkàdekè sí.+ 16  Mo sì ń gbèrò ṣáá láti mọ èyí;+ Ó jẹ́ ìdààmú ní ojú mi, 17  Títí mo fi wá sínú ibùjọsìn títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run.+ Mo fẹ́ láti fi òye mọ ọjọ́ ọ̀la wọn.+ 18  Dájúdájú, orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́ ni ibi tí ìwọ gbé wọn kà.+ Ìwọ ti mú kí wọ́n ṣubú ní rírún wómúwómú.+ 19  Ẹ wo bí wọ́n ti di ohun ìyàlẹ́nu bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!+ Ẹ wo bí wọ́n ti dé òpin wọn, tí a mú wọn wá sí òpin wọn nípasẹ̀ ìpayà òjijì! 20  Bí àlá lẹ́yìn jíjí, Jèhófà,+ Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò tẹ́ńbẹ́lú ère wọn nígbà tí ìwọ bá ru dìde.+ 21  Nítorí tí ọkàn-àyà mi di kíkorò,+ Kíndìnrín mi sì ro mí gógó,+ 22  Mo sì jẹ́ aláìnírònú, n kò sì lè mọ̀;+ Mo dà bí ẹranko lásán-làsàn ní ojú ìwòye rẹ.+ 23  Ṣùgbọ́n èmi wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo;+ Ìwọ ti di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.+ 24  Ìmọ̀ràn rẹ ni ìwọ yóò fi ṣamọ̀nà mi,+ Lẹ́yìn ìgbà náà, ìwọ yóò sì mú mi wọnú ògo pàápàá.+ 25  Ta ni mo ní ní ọ̀run?+ Yàtọ̀ sí ìwọ, èmi kò ní inú dídùn mìíràn lórí ilẹ̀ ayé.+ 26  Ẹ̀yà ara mi àti ọkàn-àyà mi ti kọṣẹ́.+ Ọlọ́run ni àpáta ọkàn-àyà mi àti ìpín mi fún àkókò tí ó lọ kánrin.+ 27  Nítorí, wò ó! àní àwọn tí ń jìnnà sí ọ yóò ṣègbé.+ Ṣe ni ìwọ yóò pa gbogbo àwọn tí ń ṣe ìṣekúṣe kúrò lọ́dọ̀ rẹ lẹ́nu mọ́.+ 28  Ṣùgbọ́n ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni mo fi ṣe ibi ìsádi mi,+ Láti máa polongo gbogbo iṣẹ́ rẹ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé