Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 72:1-20

Nípa Sólómọ́nì. 72  Ọlọ́run, fi àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ fún ọba,+ Àti òdodo rẹ fún ọmọ ọba.+   Kí ó fi òdodo gba ẹjọ́ àwọn ènìyàn rẹ rò+ Kí ó sì fi ìpinnu ìdájọ́ ṣe ti àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́.+   Kí àwọn òkè ńláńlá gbé àlàáfíà wá bá àwọn ènìyàn,+ Àti àwọn òkè kéékèèké pẹ̀lú, nípasẹ̀ òdodo.   Kí ó ṣe ìdájọ́ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ nínú àwọn ènìyàn,+ Kí ó gba àwọn ọmọ òtòṣì là, Kí ó sì tẹ àwọn oníjìbìtì rẹ́.   Wọn yóò máa bẹ̀rù rẹ níwọ̀n ìgbà tí oòrùn bá ń bẹ,+ Àti níwájú òṣùpá ní ìran dé ìran.+   Òun yóò rọ̀ sílẹ̀ bí òjò sórí koríko tí a gé,+ Bí ọ̀pọ̀ yanturu ọ̀wààrà òjò tí ń mú kí ilẹ̀ rin.+   Ní àwọn ọjọ́ rẹ̀, olódodo yóò rú jáde,+ Àti ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà títí òṣùpá kì yóò fi sí mọ́.+   Òun yóò sì ní àwọn ọmọ abẹ́ láti òkun dé òkun+ Àti láti Odò+ dé òpin ilẹ̀ ayé.+   Àwọn olùgbé ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò tẹrí ba níwájú rẹ̀,+ Àní àwọn ọ̀tá rẹ̀ yóò lá ekuru.+ 10  Àwọn ọba Táṣíṣì àti ti àwọn erékùṣù+ Wọn yóò máa san owó òde.+ Àwọn ọba Ṣébà àti ti Sébà— Wọn yóò mú ẹ̀bùn wá.+ 11  Gbogbo àwọn ọba yóò sì wólẹ̀ fún un;+ Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, ní tiwọn, yóò máa sìn ín.+ 12  Nítorí tí òun yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè,+ Ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ pẹ̀lú, àti ẹnì yòówù tí kò ní olùrànlọ́wọ́.+ 13  Òun yóò káàánú ẹni rírẹlẹ̀ àti òtòṣì,+ Yóò sì gba ọkàn àwọn òtòṣì là.+ 14  Yóò tún ọkàn wọn rà padà lọ́wọ́ ìnilára àti lọ́wọ́ ìwà ipá, Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì ṣe iyebíye ní ojú rẹ̀.+ 15  Kí ó wà pẹ́,+ kí a sì fún un lára wúrà Ṣébà.+ Kí a sì máa gba àdúrà nítorí rẹ̀ nígbà gbogbo; Kí a sì máa fi ìbùkún fún un láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.+ 16  Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀;+ Àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.+ Èso rẹ̀ yóò rí bí ti Lẹ́bánónì,+ Àwọn èyí tí ó sì ti inú ìlú ńlá wá yóò yọ ìtànná bí ewéko ilẹ̀.+ 17  Kí orúkọ rẹ̀ máa wà nìṣó fún àkókò tí ó lọ kánrin;+ Kí orúkọ rẹ̀ ní ìbísí níwájú oòrùn, Kí wọ́n sì máa bù kún ara wọn nípasẹ̀ rẹ̀;+ Kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè pè é ní aláyọ̀.+ 18  Ìbùkún ni fún Jèhófà Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì,+ Ẹni tí ó jẹ́ pé òun nìkan ṣoṣo ni ó ń ṣe àwọn iṣẹ́ àgbàyanu.+ 19  Ìbùkún sì ni fún orúkọ rẹ̀ ológo fún àkókò tí ó lọ kánrin,+ Kí ògo rẹ̀ sì kún gbogbo ilẹ̀ ayé.+ Àmín àti Àmín. 20  Àwọn àdúrà Dáfídì, ọmọkùnrin Jésè,+ ti wá sí òpin.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé