Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo ohun yíyàn míì

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yorùbá

Bíbélì Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì | ÌWÉ MÍMỌ́ NÍ ÌTUMỌ̀ AYÉ TUNTUN

Sáàmù 71:1-24

71  Ìwọ, Jèhófà, ni mo sá di.+ Kí ojú má tì mí láé.+   Nínú òdodo rẹ, kí o dá mi nídè, kí o sì pèsè àsálà fún mi.+ Dẹ etí sí mi, kí o sì gbà mí là.+   Di odi agbára tí a fi òkúta ṣe fún mi, èyí tí èmi yóò máa wọ̀ lọ nígbà gbogbo.+ Kí o pàṣẹ láti gbà mí là,+ Nítorí ìwọ ni àpáta gàǹgà mi àti ibi odi agbára mi.+   Ìwọ Ọlọ́run mi, pèsè àsálà fún mi kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú,+ Kúrò ní àtẹ́lẹwọ́ ẹni tí ń hùwà lọ́nà tí kò bá ìdájọ́ òdodo mu àti lọ́nà ìninilára.+   Nítorí ìwọ ni ìrètí mi,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, ìgbọ́kànlé mi láti ìgbà èwe mi wá.+   Ìwọ ni mo gbára lé láti inú ikùn wá;+ Ìwọ ni Ẹni tí ó yà mí sọ́tọ̀ àní láti ìhà inú ìyá mi.+ Ọ̀dọ̀ rẹ ni ìyìn mi ń lọ nígbà gbogbo.+   Mo dà bí iṣẹ́ ìyanu sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn;+ Ṣùgbọ́n ìwọ ni ibi ìsádi lílágbára mi.+   Ẹnu mi kún fún ìyìn rẹ,+ Láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀ fún ẹwà rẹ.+   Má ṣe gbé mi sọnù ní àkókò ọjọ́ ogbó;+ Ní àkókò náà tí agbára mi ń kùnà, má ṣe fi mí sílẹ̀.+ 10  Nítorí tí àwọn ọ̀tá mi ti sọ nípa mi,+ Àní àwọn tí ń ṣọ́ ọkàn mi ti jọ gbìmọ̀ pọ̀,+ 11  Wọ́n wí pé: “Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ti fi í sílẹ̀.+ Ẹ lépa rẹ̀ kí ẹ sì mú un, nítorí tí kò sí olùdáǹdè.”+ 12  Ọlọ́run, má jìnnà réré sí mi.+ Ìwọ Ọlọ́run mi, ṣe wéré láti wá ṣe ìrànwọ́ fún mi.+ 13  Kí ojú tì wọ́n, kí wọ́n wá sí òpin wọn, àwọn tí ń tako ọkàn mi.+ Kí wọ́n fi ẹ̀gàn àti ìtẹ́lógo bo ara wọn, àwọn tí ń wá ìyọnu àjálù fún mi.+ 14  Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa dúró nígbà gbogbo,+ Ṣe ni èmi yóò sì máa fi kún gbogbo ìyìn rẹ. 15  Ẹnu mi yóò máa ròyìn òdodo rẹ lẹ́sẹẹsẹ,+ Ìgbàlà rẹ láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀,+ Nítorí pé èmi kò mọ iye wọn.+ 16  Èmi yóò wá nínú agbára ńlá tí ó tóbi lọ́lá,+ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ;+ Èmi yóò máa mẹ́nu kan òdodo rẹ, tìrẹ nìkan.+ 17  Ọlọ́run, ìwọ ti kọ́ mi láti ìgbà èwe mi wá,+ Títí di ìsinsìnyí, mo sì ń bá a nìṣó ní sísọ nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.+ 18  Àní títí di ọjọ́ ogbó àti orí ewú, Ọlọ́run, má fi mí sílẹ̀,+ Títí èmi yóò fi lè sọ nípa apá rẹ fún ìran náà,+ Fún gbogbo àwọn tí ń bọ̀, nípa agbára ńlá rẹ.+ 19  Ọlọ́run, òdodo rẹ ga títí dé ibi gíga lókè;+ Ní ti àwọn ohun ńlá tí ìwọ ti ṣe,+ Ọlọ́run, ta ní dà bí rẹ?+ 20  Nítorí pé ìwọ ti mú kí n rí ọ̀pọ̀ wàhálà àti ìyọnu àjálù,+ Kí o tún mú mi sọ jí;+ Kí o sì tún mú mi gòkè wá láti inú ibú omi ilẹ̀ ayé.+ 21  Kí o sọ títóbi mi di ńlá,+ Kí o yí mi ká, kí o sì tù mí nínú.+ 22  Èmi pẹ̀lú, èmi yóò máa fi ohun èlò orin olókùn tín-ín-rín gbé ọ lárugẹ,+ Ní ti òótọ́ rẹ, ìwọ Ọlọ́run mi.+ Ṣe ni èmi yóò máa fi háàpù kọ orin atunilára sí ọ, ìwọ Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.+ 23  Ètè mi yóò máa fi ìdùnnú ké jáde nígbà tí mo bá fẹ́ láti kọ orin atunilára sí ọ,+ Àní ọkàn mi tí ìwọ ti tún rà padà.+ 24  Pẹ̀lúpẹ̀lù, ahọ́n mi, láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, yóò máa sọ òdodo rẹ jáde ní ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́,+ Nítorí pé ìtìjú ti bá wọn, nítorí pé wọ́n ti tẹ́, àwọn tí ń wá ìyọnu àjálù fún mi.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé