Sáàmù 70:1-5
Sí olùdarí. Ti Dáfídì, láti mú wá sí ìrántí.+
70 Ọlọ́run, ṣe kánkán láti dá mi nídè,+Jèhófà, ṣe kánkán láti wá ṣe ìrànwọ́ fún mi.+
2 Kí ojú tì wọ́n, kí wọ́n sì tẹ́, àwọn tí ń wá ọkàn mi.+Kí wọ́n yí padà, kí a sì tẹ́ wọn lógo, àwọn tí ó ní inú dídùn sí ìyọnu àjálù mi.+
3 Kí wọ́n padà lọ nítorí ìtìjú wọn, àwọn tí ń wí pé: “Àháà, àháà!”+
4 Kí wọ́n máa yọ ayọ̀ ńláǹlà, kí wọ́n sì máa yọ̀ nínú rẹ, gbogbo àwọn tí ń wá ọ,+Kí wọ́n sì máa wí nígbà gbogbo pé: “Kí Ọlọ́run di àgbégalọ́lá!”—àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ ìgbàlà rẹ.+
5 Ṣùgbọ́n ẹni tí a ń ṣẹ́ níṣẹ̀ẹ́ àti òtòṣì ni mí.+Ọlọ́run, tètè gbé ìgbésẹ̀ nítorí mi.+Ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi àti Olùpèsè àsálà fún mi.+Jèhófà, má ṣe pẹ́ jù.+