Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Yan èdè Yorùbá

Sáàmù 7:1-17

Orin arò ti Dáfídì, èyí tí ó kọ sí Jèhófà nípa àwọn ọ̀rọ̀ Kúṣì tí í ṣe ọmọ Bẹ́ńjámínì. 7  Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi,+ ìwọ ni mo sá di.+Gbà mí là lọ́wọ́ gbogbo àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí mi, kí o sì dá mi nídè,+   Kí ẹnikẹ́ni má bàa fa ọkàn mi ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ bí kìnnìún ti ń ṣe,+Já mi gbà nígbà tí kò bá sí olùdáǹdè.+   Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, bí mo bá ti ṣe èyí,+Bí àìṣèdájọ́ òdodo èyíkéyìí bá wà ní ọwọ́ mi,+   Bí mo bá ti fi ohun búburú san án padà fún ẹni tí ń san mí lẹ́san,+Tàbí kẹ̀, bí mo bá ti fi ẹni tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi láìkẹ́sẹ járí ṣe ìjẹ,+   Jẹ́ kí ọ̀tá máa lépa ọkàn mi,+Sì jẹ́ kí ó bá ẹ̀mí mi, kí ó sì tẹ̀ ẹ́ mọ́ ilẹ̀yílẹ̀,Sì mú kí ògo mi máa gbé inú ekuru pàápàá. Sélà.   Dìde, Jèhófà, nínú ìbínú rẹ;+Gbé ara rẹ sókè nítorí ìbújáde ìbínú kíkan àwọn tí ń fi ẹ̀tanú hàn sí mi,+Jí fún mi,+ níwọ̀n bí o ti pàṣẹ ìdájọ́ pàápàá.+   Kí àpéjọ àwọn àwùjọ orílẹ̀-èdè sì yí ọ ká,Kí o sì padà sí ibi gíga lókè ní ìdojú-ìjà-kọ ọ́.   Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn.+Ṣe ìdájọ́ mi, Jèhófà, ní ìbámu pẹ̀lú òdodo mi+Àti ní ìbámu pẹ̀lú ìwà títọ́+ mi tí ó wà nínú mi.   Jọ̀wọ́, kí ìwà búburú àwọn ẹni burúkú wá sí òpin,+Kí o sì fìdí olódodo múlẹ̀;+Ọlọ́run, tí ó jẹ́ olódodo,+ sì ń dán ọkàn-àyà+ àti àwọn kíndìnrín+ wò. 10  Apata tí ń bẹ fún mi wà lọ́dọ̀ Ọlọ́run,+ Olùgbàlà àwọn adúróṣánṣán ní ọkàn-àyà.+ 11  Ọlọ́run jẹ́ Onídàájọ́ òdodo,+Ọlọ́run sì ń fi ìdálẹ́bi sọ̀kò lójoojúmọ́. 12  Bí ẹnikẹ́ni kò bá padà,+ Òun yóò pọ́n idà rẹ̀,+Dájúdájú, òun yóò fa ọrun rẹ̀, yóò sì múra rẹ̀ sílẹ̀ fún títa.+ 13  Òun yóò sì pèsè àwọn ohun èlò ikú sílẹ̀ fún ara rẹ̀;+Òun yóò ṣe àwọn ọfà rẹ̀ ní èyí tí ń jó fòfò.+ 14  Wò ó! Ẹnì kan ń bẹ tí ó lóyún ohun tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́,+Ó sì ti lóyún ìjàngbọ̀n, ó sì dájú pé yóò bí èké.+ 15  Ó ti wa kòtò, ó sì tẹ̀ síwájú láti gbẹ́ ẹ;+Ṣùgbọ́n òun yóò já sínú ihò tí ó ti gbẹ́.+ 16  Ìjàngbọ̀n rẹ̀ yóò padà sí orí òun fúnra rẹ̀,+Àtàrí rẹ̀ sì ni ìwà ipá òun fúnra rẹ̀ yóò sọ̀ kalẹ̀ sí.+ 17  Èmi yóò gbé Jèhófà lárugẹ gẹ́gẹ́ bí òdodo rẹ̀,+Ṣe ni èmi yóò máa kọ orin atunilára sí orúkọ+ Jèhófà Ẹni Gíga Jù Lọ.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé